Àwọn Ọba Kinni 20:26-32 BM

26 Ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ní ìbẹ̀rẹ̀ àkókò òjò, ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó sì kó wọn lọ sí ìlú Afeki, láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli.

27 Wọ́n kó àwọn ọmọ ogun Israẹli náà jọ, wọ́n sì wá àwọn ohun ìjà ogun fún wọn. Àwọn náà jáde sójú ogun, wọ́n pàgọ́ tiwọn siwaju àwọn ọmọ ogun Siria, wọ́n wá dàbí agbo ewúrẹ́ meji kéékèèké níwájú àwọn ọmọ ogun Siria tí wọ́n tò lọ rẹrẹẹrẹ ninu pápá.

28 Wolii kan tọ Ahabu lọ, ó sì wí fún un pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ‘Nítorí pé àwọn ará Siria sọ pé, “ọlọrun orí òkè ni OLUWA, kì í ṣe Ọlọrun àfonífojì,” nítorí náà ni n óo ṣe fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí ọ̀pọ̀ eniyan wọnyi, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

29 Àgọ́ àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti àwọn ọmọ ogun Siria kọjú sí ara wọn, wọn kò sì kúrò ní ààyè wọn fún ọjọ́ meje. Nígbà tí ó di ọjọ́ keje wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jagun. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pa ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn lára àwọn ti Siria ní ọjọ́ kan.

30 Àwọn ọmọ ogun Siria yòókù sì sá lọ sí ìlú Afeki; odi ìlú náà sì wó pa ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaarin (27,000) tí ó kù ninu wọn.Benhadadi pàápàá sá wọ inú ìlú lọ, ó sì sá pamọ́ sinu yàrá ní ilé kan.

31 Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wí fún un pé, “A gbọ́ pé àwọn ọba Israẹli a máa ní ojú àánú, jẹ́ kí á sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́dìí, kí á wé okùn mọ́ ara wa lórí, kí á sì lọ sọ́dọ̀ ọba Israẹli, bóyá yóo dá ẹ̀mí rẹ sí.”

32 Nítorí náà, wọ́n sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́dìí, wọ́n sì wé okùn mọ́ ara wọn lórí. Wọ́n bá tọ Ahabu ọba lọ, wọ́n ní, “Benhadadi, iranṣẹ rẹ, ní kí á jíṣẹ́ fún ọ pé kí o jọ̀wọ́ kí o dá ẹ̀mí òun sí.”Ahabu bá dáhùn pé, “Ó ṣì wà láàyè? Arakunrin mi ni!”