34 Benhadadi bá wí fún un pé, “N óo dá àwọn ìlú tí baba mi gbà lọ́wọ́ baba rẹ pada fún ọ, o óo sì lè kọ́ àwọn ilé ìtajà fún ara rẹ ní ìlú Damasku gẹ́gẹ́ bí baba mi ti ṣe ní ìlú Samaria.”Ahabu dá a lóhùn pé, “Bí o bá ṣe ohun tí o wí yìí, n óo dá ọ sílẹ̀.” Ahabu bá bá a dá majẹmu, ó sì fi sílẹ̀ kí ó máa lọ.
35 OLUWA pàṣẹ fún ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wolii kan, pé kí ó sọ fún wolii ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan pé kí ó jọ̀wọ́ kí ó lu òun, ṣugbọn wolii náà kọ̀, kò lù ú.
36 Ni ó bá wí fún un pé, “Nítorí pé o ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, bí o bá ti ń kúrò lọ́dọ̀ mi gẹ́lẹ́ ni kinniun yóo pa ọ́.” Bí ó sì ti kúrò lóòótọ́, kinniun kan yọ sí i, ó sì pa á.
37 Wolii yìí rí ọkunrin mìíràn, o sì bẹ̀ ẹ́ pé, “Lù mí.” Ọkunrin yìí lù ú, lílù náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi pa á lára.
38 Wolii yìí bá mú aṣọ kan, ó fi wé ojú rẹ̀. Ó yíra pada, kí ẹnikẹ́ni má baà mọ̀ ọ́n, ó sì lọ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà de ìgbà tí ọba Israẹli yóo kọjá.
39 Bí ọba ti ń kọjá lọ, wolii yìí kígbe pé, “Kabiyesi, nígbà tí mò ń jà lójú ogun, ọmọ ogun ẹlẹgbẹ́ mi kan mú ọ̀tá kan tí ó mú ní ìgbèkùn wá sọ́dọ̀ mi, ó ní kí n máa ṣọ́ ọkunrin yìí, ó ní bí ó bá sá lọ, èmi ni n óo kú dípò rẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, mo níláti san ìwọ̀n talẹnti fadaka kan gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn.
40 Ṣugbọn níbi tí mo ti ń lọ sókè sódò, tí mò ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn, ọkunrin yìí sá lọ.”Ọba dá a lóhùn pé, “Ìwọ náà ti dá ara rẹ lẹ́jọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni yóo sì rí.”