4 Ahabu ọba bá ranṣẹ pada pé, “Gẹ́gẹ́ bí o ti sọ, oluwa mi, ìwọ ni o ni mí ati gbogbo ohun tí mo ní.”
5 Àwọn oníṣẹ́ náà tún pada wá sí ọ̀dọ̀ Ahabu, wọ́n ní Benhadadi ọba tún ranṣẹ, ó ní, òun ti ranṣẹ sí Ahabu pé kí ó kó fadaka rẹ̀ ati wúrà rẹ̀, ati àwọn obinrin rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀ fún òun,
6 ṣugbọn òun óo rán àwọn oníṣẹ́ òun sí i ní ìwòyí ọ̀la láti yẹ ààfin rẹ̀ wò ati ilé àwọn oníṣẹ́ rẹ̀, kí wọ́n sì kó ohunkohun tí ó bá wù wọ́n.
7 Nígbà náà ni Ahabu ọba ranṣẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà, ó wí fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí i pé ọkunrin yìí ń wá ìjàngbọ̀n? Ó ranṣẹ wá pé kí n kó fadaka ati wúrà mi, ati àwọn obinrin mi, ati àwọn ọmọ mi fún òun, n kò sì bá a jiyàn.”
8 Àwọn àgbààgbà bá dá a lóhùn pé, “Má dá a lóhùn rárá, má sì gbà fún un.”
9 Ahabu bá ranṣẹ pada sí Benhadadi ọba pé, “Mo faramọ́ ohun tí ó kọ́kọ́ bèèrè fún, ṣugbọn n kò lè gba ti ẹẹkeji yìí.”Àwọn oníṣẹ́ náà pada lọ jíṣẹ́ fún Benhadadi ọba.
10 Benhadadi ọba tún ranṣẹ pada pé, “Àwọn oriṣa ń gbọ́! Mò ń kó àwọn eniyan bọ̀ láti pa ìlú Samaria run, wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé ọwọ́ lásán ni wọn yóo fi kó gbogbo erùpẹ̀ ìlú náà. Bí kò bá rí bẹ́ẹ̀, kí àwọn oriṣa pa mí.”