12 Nítorí náà, fún mi ní òkè yìí, tí OLUWA sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ọjọ́ náà, nítorí pé ìwọ náà gbọ́ ní ọjọ́ náà pé, àwọn ọmọ Anakimu wà níbẹ̀. Ìlú wọn tóbi, wọ́n sì jẹ́ ìlú olódi, ó ṣeéṣe kí OLUWA wà pẹlu mi kí n sì lè lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti wí.”
13 Joṣua bá súre fún Kalebu ọmọ Jefune, ó sì fún un ní òkè Heburoni, bí ìpín tirẹ̀.
14 Bẹ́ẹ̀ ni Heburoni di ilẹ̀ ìní Kalebu, ọmọ Jefune, ará Kenisi títí di òní olónìí, nítorí pé ó fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun Israẹli.
15 Orúkọ Heburoni tẹ́lẹ̀ ni Kiriati Ariba; Ariba yìí ni ẹni tí ó jẹ́ alágbára jùlọ ninu àwọn òmìrán tí à ń pè ní Anakimu.Àwọn eniyan náà sì sinmi ogun jíjà ní ilẹ̀ náà.