5 Bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose gan-an ni àwọn ọmọ Israẹli ṣe pín ilẹ̀ náà.
6 Ní ọjọ́ kan àwọn ẹ̀yà Juda wá sí ọ̀dọ̀ Joṣua ní Giligali. Ọkunrin kan ninu wọn tí ń jẹ́ Kalebu, ọmọ Jefune, ará Kenisi bá sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ ohun tí OLUWA sọ fún Mose eniyan Ọlọrun ní Kadeṣi Banea nípa àwa mejeeji?
7 Ẹni ogoji ọdún ni mí nígbà tí Mose iranṣẹ OLUWA rán mi láti Kadeṣi Banea láti ṣe amí ilẹ̀ náà. Bí ọkàn mi ti rí gan-an nígbà náà ni mo ṣe ròyìn fún un.
8 Ṣugbọn àwọn arakunrin mi tí a jọ lọ dáyàjá àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn èmi fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun mi.
9 Mose bá búra ní ọjọ́ náà pé, ‘Dájúdájú, gbogbo ibi tí ẹsẹ̀ rẹ ti tẹ̀ ni yóo jẹ́ ìpín fún ọ ati fún àwọn ọmọ rẹ títí lae, nítorí pé o ti fi tọkàntọkàn tẹ̀lé OLUWA Ọlọrun mi.’
10 OLUWA ti dá ẹ̀mí mi sí, gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, láti nǹkan bí ọdún marunlelogoji tí OLUWA ti sọ ọ̀rọ̀ yìí fún Mose nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ń rìn ninu aṣálẹ̀. Nisinsinyii, mo ti di ẹni ọdún marundinlaadọrun,
11 bí agbára mi ṣe rí nígbà tí Mose rán wa jáde láti lọ ṣe amí, bẹ́ẹ̀ náà ni ó wà títí di òní olónìí, mo tún lágbára láti jagun ati láti wọlé ati láti jáde.