22 Joṣua bá ranṣẹ, wọ́n sáré lọ wo inú àgọ́ rẹ̀, wọ́n bá àwọn nǹkan náà ní ibi tí ó bò wọ́n mọ́, ó fi fadaka tẹ́lẹ̀.
23 Wọ́n hú wọn jáde ninu àgọ́ rẹ̀, wọ́n kó wọn wá siwaju Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì tẹ́ wọn kalẹ̀ níwájú OLUWA.
24 Joṣua ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá mú Akani, ọmọ Sera, ati fadaka, ati ẹ̀wù àwọ̀lékè, ati ọ̀pá wúrà, ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin, àwọn akọ mààlúù rẹ̀ ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, àwọn aguntan rẹ̀ ati àgọ́ rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní, wọ́n kó wọn lọ sí àfonífojì Akori.
25 Joṣua bá bi í pé, “Kí ló dé tí o fi kó wa sinu gbogbo ìyọnu yìí? OLUWA sì ti kó ìyọnu bá ìwọ náà lónìí.” Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá sọ wọ́n ní òkúta pa, wọ́n sì dáná sun wọ́n.
26 Wọ́n kó òkítì òkúta jọ sórí rẹ̀. Òkítì òkúta náà sì wà níbẹ̀ títí di òní olónìí.OLUWA bá yí ibinu rẹ̀ pada. Nítorí náà ni wọ́n ṣe ń pe ibẹ̀ ní àfonífojì Akori.