15 Nígbà tí àwọn ọ̀tá wa ti gbọ́ pé a ti mọ àṣírí ète wọn, ati pé Ọlọrun ti da ìmọ̀ wọn rú, gbogbo wa pada sí ibi odi náà, olukuluku sì ń ṣe iṣẹ́ tirẹ̀.
16 Láti ọjọ́ náà, ìdajì àwọn òṣìṣẹ́ mi ní ń bá iṣẹ́ odi mímọ lọ, ìdajì yòókù sì dira pẹlu ọ̀kọ̀, àṣíborí, ọrun ati aṣọ ogun. Àwọn ìjòyè sì wà lẹ́yìn gbogbo àwọn eniyan Juda,
17 tí ń mọ odi lọ́wọ́. Àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ ń fi ọwọ́ kan ṣiṣẹ́, wọ́n sì mú ohun ìjà ní ọwọ́ keji.
18 Ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu àwọn tí wọn ń ṣiṣẹ́ náà fi idà kọ́ èjìká bí ó ṣe ń mọ odi lọ. Ẹni tí ó ń fọn fèrè sì wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀dọ̀ mi.
19 Mo sì sọ fún àwọn ọlọ́lá ati àwọn ìjòyè ati àwọn eniyan yòókù pé, “Iṣẹ́ náà pọ̀ gan-an, odi yìí sì gùn tóbẹ́ẹ̀ tí ó mú kí á jìnnà sí ara wa.
20 Ibikíbi tí ẹ bá wà, tí ẹ bá ti gbọ́ fèrè, ẹ wá péjọ sọ́dọ̀ wa. Ọlọrun wa yóo jà fún wa.”
21 Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe ń ṣe iṣẹ́ náà tí àwọn apá kan sì gbé idà lọ́wọ́ láti àárọ̀ di alẹ́.