Samuẹli Keji 20:1-7 BM

1 Aláìníláárí ẹ̀dá kan wà ní ààrin àwọn ará Giligali tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikiri, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ọkunrin yìí fọn fèrè, ó ní,“Kò sí ohun tí ó kàn wá pẹlu Dafidi,a kò sì ní ìpín nílé ọmọ Jese.Ẹ pada sí ilé yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.”

2 Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada lẹ́yìn Dafidi, wọ́n tẹ̀lé Ṣeba. Ṣugbọn àwọn eniyan Juda tẹ̀lé Dafidi, ọba wọn, pẹlu ẹ̀mí òtítọ́, láti odò Jọdani títí dé Jerusalẹmu.

3 Nígbà tí Dafidi pada dé ààfin rẹ̀ ní Jerusalẹmu, ó mú àwọn obinrin rẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó fi sílẹ̀, pé kí wọ́n máa tọ́jú ààfin, ó fi wọ́n sinu ilé kan pẹlu olùṣọ́, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún wọn, ṣugbọn kò bá wọn lòpọ̀ mọ́. Ninu ìhámọ́ ni wọ́n wà, tí wọ́n ń gbé bí opó, títí tí wọ́n fi kú.

4 Lẹ́yìn náà, ọba sọ fún Amasa pé, “Pe gbogbo àwọn ọkunrin Juda jọ, kí o sì kó wọn wá sọ́dọ̀ mi láàrin ọjọ́ mẹta; kí ìwọ náà sì wá.”

5 Amasa bá lọ kó àwọn eniyan Juda jọ, ṣugbọn kò dé títí àkókò tí ọba dá fún un fi kọjá.

6 Ọba bá pe Abiṣai, ó ní, “Ìyọnu tí Ṣeba yóo kó bá wa yóo ju ti Absalomu lọ. Nítorí náà, kó àwọn eniyan mi lẹ́yìn kí o sì máa lépa rẹ̀ lọ. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè gba àwọn ìlú olódi bíi mélòó kan kí ó sì dá wahala sílẹ̀ fún wa.”

7 Gbogbo àwọn ọmọ ogun Joabu, ati àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun yòókù, tí wọ́n kù ní Jerusalẹmu bá tẹ̀lé Abiṣai láti lépa Ṣeba.