14 Arakunrin baba rẹ̀ rí òun ati iranṣẹ rẹ̀, ó bi wọ́n pé, “Níbo ni ẹ ti lọ?”Saulu dáhùn pé, “Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni a wá lọ. Nígbà tí a wá wọn tí a kò rí wọn, a lọ sọ́dọ̀ Samuẹli.”
15 Arakunrin baba Saulu bá bi í pé, “Kí ni Samuẹli sọ fun yín?”
16 Saulu dáhùn pé, “Ó sọ fún wa pé, dájúdájú, wọ́n ti rí àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà.” Ṣugbọn Saulu kò sọ fún un pé, Samuẹli sọ fún òun pé òun yóo jọba.
17 Samuẹli pe àwọn eniyan náà jọ siwaju OLUWA ní Misipa.
18 Ó sọ fún wọn pé, “OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Mo kó yín jáde wá láti Ijipti, mo gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati gbogbo àwọn eniyan yòókù tí wọn ń ni yín lára.’
19 Ṣugbọn nisinsinyii ẹ ti kọ Ọlọrun yín sílẹ̀, Ọlọrun tí ó gbà yín kúrò lọ́wọ́ ìṣòro ati ìyọnu. Ẹ wí fún mi pé, ‘Yan ẹnìkan, tí yóo jọba lórí wa.’ Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tò kọjá níwájú OLUWA ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.”
20 Nígbà náà ni, Samuẹli mú kí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan tò kọjá níwájú OLUWA, gègé sì mú ẹ̀yà Bẹnjamini.