1 Nahaṣi, ọba Amoni, kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ gbógun ti ìlú Jabeṣi Gileadi. Àwọn ará Jabeṣi bá sọ fún Nahaṣi pé, “Jẹ́ kí á jọ dá majẹmu, a óo sì máa sìn ọ́.”
2 Nahaṣi dá wọn lóhùn pé, “Ohun tí mo fi lè ba yín dá majẹmu ni pé, kí n yọ ojú ọ̀tún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín, kí ó lè jẹ́ ìtìjú fún gbogbo Israẹli.”
3 Àwọn àgbààgbà Jabeṣi dáhùn pé, “Fún wa ní ọjọ́ meje, kí á lè ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli. Bí kò bá sí ẹni tí yóo gbà wá, a óo jọ̀wọ́ ara wa fún ọ.”
4 Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ náà dé Gibea, níbi tí Saulu ń gbé, wọ́n ròyìn fún àwọn ará ìlú náà, gbogbo wọn sì pohùnréré ẹkún.
5 Ní àkókò yìí gan-an ni Saulu ń ti oko rẹ̀ bọ̀, pẹlu àwọn akọ mààlúù rẹ̀. Ó bèèrè pé, “Kí ló ṣẹlẹ̀ tí gbogbo eniyan fi ń sọkún?” Wọ́n bá sọ ohun tí àwọn ará Jabeṣi sọ fún un.
6 Nigba tí Saulu gbọ́ èyí, ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Saulu inú sì bí i gidigidi.
7 Ó mú akọ mààlúù meji, ó gé wọn sí wẹ́wẹ́, ó fi wọ́n ranṣẹ jákèjádò ilẹ̀ Israẹli, pẹlu ìkìlọ̀ pé, “Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹ̀lé Saulu ati Samuẹli lọ sójú ogun, bí a óo ti ṣe àwọn akọ mààlúù rẹ̀ nìyí.”Ìbẹ̀rù OLUWA mú àwọn ọmọ Israẹli, gbogbo wọn patapata jáde láì ku ẹnìkan.