9 Nítorí náà, Saulu ní kí wọ́n gbé ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia wá fún òun, ó sì rú ẹbọ.
10 Bí ó ti parí rírú ẹbọ sísun náà tán ni Samuẹli dé. Saulu lọ pàdé rẹ̀, ó sì kí i káàbọ̀.
11 Ṣugbọn Samuẹli wí fún un pé, “Kí lo dánwò yìí?” Saulu bá dá a lóhùn pé, “Àwọn eniyan náà ti bẹ̀rẹ̀ sí sá kúrò lẹ́yìn mi, o kò sì dé ní àkókò tí o dá. Àwọn ará Filistia sì ti kó ara wọn jọ ní Mikimaṣi.
12 Mo wá rò ó wí pé, àwọn ará Filistia tí ń bọ̀ wá gbógun tì mí ní Giligali níhìn-ín, n kò sì tíì wá ojurere OLUWA. Ni mo bá rú ẹbọ sísun.”
13 Samuẹli bá wí fún un pé, “Ìwà òmùgọ̀ patapata gbáà ni èyí. O kò pa òfin tí OLUWA Ọlọrun rẹ fún ọ mọ́. Bí ó bá jẹ́ pé o gbọ́ tirẹ̀ ni, nisinsinyii ni OLUWA ìbá fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Israẹli títí lae.
14 Ṣugbọn nisinsinyii, ìjọba rẹ kò ní jẹ́ títí lae, nítorí pé, o ti ṣe àìgbọràn sí OLUWA. Ó ti wá ẹni tí ó fẹ́, ó sì ti yàn án láti jẹ́ olórí fún àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé, o kò pa òfin OLUWA rẹ mọ́.”
15 Samuẹli kúrò ní Giligali, ó lọ sí Gibea ní Bẹnjamini. Saulu ka àwọn eniyan tí wọ́n kù lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n jẹ́ ẹgbẹta (600).