13 Samuẹli bá lọ sọ́dọ̀ Saulu. Saulu sọ fún un pé, “Kí OLUWA kí ó bukun ọ, Samuẹli, mo ti pa òfin OLUWA mọ́.”
14 Samuẹli bá bi í pé, “Èwo ni igbe àwọn aguntan ati ti àwọn mààlúù tí mò ń gbọ́ yìí?”
15 Saulu dá a lóhùn pé, “Àwọn eniyan mi ni wọ́n kó wọn lọ́dọ̀ àwọn ará Amaleki. Wọ́n ṣa àwọn aguntan ati àwọn mààlúù tí wọ́n dára jùlọ pamọ́ láti fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun rẹ. A sì ti pa gbogbo àwọn yòókù run patapata.”
16 Samuẹli bá sọ fún un pé, “Dákẹ́! Jẹ́ kí n sọ ohun tí OLUWA wí fún mi ní alẹ́ àná fún ọ.”Saulu dáhùn pé, “Mò ń gbọ́.”
17 Samuẹli ní, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o kò jámọ́ nǹkankan lójú ara rẹ, sibẹsibẹ ìwọ ni olórí gbogbo ẹ̀yà Israẹli. Ìwọ ni OLUWA fi òróró yàn ní ọba wọn.
18 Ó sì rán ọ jáde pẹlu àṣẹ pé kí o pa gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ará Amaleki run. Ó ní kí o gbógun tì wọ́n títí o óo fi pa wọ́n run patapata.
19 Kí ló dé tí o kò fi pa àṣẹ OLUWA mọ? Kí ló dé tí o fi kó ìkógun, tí o sì ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA?”