1 Saulu sọ fún ọmọ rẹ̀ Jonatani ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé kí wọ́n pa Dafidi. Ṣugbọn Jonatani fẹ́ràn Dafidi lọpọlọpọ.
2 Ó sì sọ fún Dafidi pé, “Baba mi fẹ́ pa ọ́, nítorí náà fi ara pamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan lọ́la, kí o má ṣe wá sí gbangba.
3 N óo dúró pẹlu baba mi ní orí pápá lọ́la níbi tí o bá farapamọ́ sí, n óo sì bá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ, ohunkohun tí mo bá sì gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, n óo sọ fún ọ.”
4 Jonatani sọ̀rọ̀ Dafidi ní rere níwájú Saulu, ó wí pé, “Kabiyesi, má ṣe nǹkankan burúkú sí iranṣẹ rẹ, Dafidi, nítorí kò ṣe ibi kan sí ọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo nǹkan tí ń ṣe ni ó ń jẹ́ ìrànlọ́wọ́ fún ọ.
5 Ó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu láti pa Goliati, OLUWA sì ṣẹ́ ogun ńlá fún Israẹli. Nígbà tí o rí i inú rẹ dùn. Kí ló dé tí o fi ń wá ọ̀nà láti pa Dafidi láìṣẹ̀?”
6 Saulu gbọ́rọ̀ sí Jonatani lẹ́nu, ó sì búra ní orúkọ OLUWA pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, n kò ní pa á.”
7 Jonatani pe Dafidi ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un. Ó mú Dafidi wá siwaju ọba, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ iranṣẹ fún ọba bíi ti àtẹ̀yìnwá.