11 Ní alẹ́ ọjọ́ náà, Saulu rán àwọn iranṣẹ kan láti máa ṣọ́ ilé Dafidi kí wọ́n lè pa á ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Ṣugbọn Mikali iyawo rẹ̀ sọ fún Dafidi pé, “Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ ní alẹ́ yìí, nítorí pé bí o bá di ọ̀la níbí, wọn yóo pa ọ́.”
12 Mikali bá sọ Dafidi kalẹ̀ láti ojú fèrèsé kan, ó sì sá lọ láti fi ara pamọ́.
13 Mikali sì mú ère kan, ó tẹ́ ẹ sórí ibùsùn, ó gbé ìrọ̀rí onírun ewúrẹ́ sibẹ, ó fi ṣe ìrọ̀rí rẹ̀, ó sì fi aṣọ bò ó.
14 Nígbà tí àwọn iranṣẹ Saulu dé láti mú Dafidi, Mikali sọ fún wọn pé, “Ara rẹ̀ kò yá.”
15 Saulu tún rán àwọn iranṣẹ náà lọ wo Dafidi, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ gbé e wá fún mi ti òun ti ibùsùn rẹ̀, kí n pa á.”
16 Nígbà tí àwọn iranṣẹ náà dé, wọ́n bá ère ní orí ibùsùn pẹlu ìrọ̀rí onírun ewúrẹ́ ní ìgbèrí rẹ̀.
17 Saulu sì bèèrè lọ́wọ́ Mikali pé, “Kí ló dé tí o fi tàn mí, tí o sì jẹ́ kí ọ̀tá mi sá àsálà?”Mikali dá Saulu lóhùn pé, “Ó sọ wí pé òun yóo pa mí bí n kò bá jẹ́ kí òun sá lọ.”