26 Sibẹ Saulu kò sọ nǹkankan nítorí pé ó rò pé bóyá nǹkankan ti ṣẹlẹ̀ sí Dafidi, tí ó sì sọ ọ́ di aláìmọ́ ni.
27 Ní ọjọ́ keji àjọ̀dún oṣù tuntun, ìjókòó Dafidi tún ṣófo. Nígbà náà ni Saulu bèèrè lọ́wọ́ Jonatani pé, “Kí ló dé tí ọmọ Jese kò wá sí ibi oúnjẹ lánàá ati lónìí?”
28 Jonatani dáhùn pé, “Ó gbààyè lọ́wọ́ mi láti lọ sí Bẹtilẹhẹmu.
29 Ó sọ pé, àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti pa á láṣẹ fún òun láti wá sí ibi àjọ̀dún ẹbọ ọdọọdún ti ìdílé wọn. Ó sì tọrọ ààyè lọ́wọ́ mi pé òun fẹ́ wà pẹlu àwọn ìdílé òun ní àkókò àjọ̀dún náà. Òun ni kò fi lè wá síbi àsè ọba.”
30 Inú bí Saulu gidigidi sí Jonatani, ó ní, “Ìwọ ọmọ ọlọ̀tẹ̀ ati aláìgbọràn obinrin yìí, mo mọ̀ wí pé ò ń gbè lẹ́yìn Dafidi, o sì ń ta àbùkù ara rẹ ati ìhòòhò ìyá rẹ.
31 Ṣé o kò mọ̀ wí pé níwọ̀n ìgbà tí ọmọ Jese bá wà láàyè, o kò lè jọba ní Israẹli kí ìjọba rẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀? Yára nisinsinyii kí o ranṣẹ lọ mú un wá; dandan ni kí ó kú.”
32 Jonatani sì dáhùn pé, “Kí ló dé tí yóo fi kú? Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀?”