39 Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé Nabali ti kú, ó ní, “Ìyìn ni fún OLUWA tí ó gbẹ̀san lára Nabali nítorí àfojúdi tí ó ṣe sí mi. Ìyìn ni fún OLUWA tí ó sì fa èmi iranṣẹ rẹ̀ sẹ́yìn kúrò ninu ṣíṣe ibi. OLUWA ti jẹ Nabali níyà fún ìwà burúkú rẹ̀.”Dafidi bá ranṣẹ sí Abigaili pé òun fẹ́ fẹ́ ẹ.
40 Àwọn iranṣẹ Dafidi lọ sọ́dọ̀ Abigaili ní Kamẹli, wọ́n ní, “Dafidi ní kí á mú ọ wá, kí o lè jẹ́ aya òun.”
41 Abigaili bá wólẹ̀ ó ní, “Iranṣẹ Dafidi ni mí, mo sì ti ṣetán láti ṣan ẹsẹ̀ àwọn iranṣẹ rẹ̀.”
42 Ó yára gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, òun pẹlu àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ marun-un, wọ́n sì tẹ̀lé àwọn iranṣẹ Dafidi lọ, Abigaili sì di aya Dafidi.
43 Dafidi ti fẹ́ Ahinoamu ará Jesireeli, ó sì tún fẹ́ Abigaili pẹlu.
44 Ṣugbọn Saulu ti mú Mikali, ọmọ rẹ̀ tí ó jẹ́ iyawo Dafidi, ó ti fún Paliti ọmọ Laiṣi tí ó wá láti Galimu pé kí ó fi ṣe aya.