1 Àwọn ọkunrin kan, ará Sifi lọ sọ fún Saulu ní Gibea pé, “Dafidi farapamọ́ sí òkè Hakila tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jeṣimoni.”
2 Lẹsẹkẹsẹ, Saulu mú ẹgbẹẹdogun (3,000) akọni ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n lọ wá Dafidi ninu aṣálẹ̀ Sifi.
3 Wọ́n pabùdó wọn sí ẹ̀bá ọ̀nà ní òkè Hakila, Dafidi sì wà ninu aṣálẹ̀ náà. Nígbà tí Dafidi mọ̀ pé Saulu ń wá òun kiri,
4 ó rán amí láti rí i dájú pé Saulu wà níbẹ̀.
5 Dafidi lọ lẹsẹkẹsẹ láti rí ibi tí Saulu ati Abineri, ọmọ Neri, olórí ogun Saulu, dùbúlẹ̀ sí. Saulu wà ninu àgọ́, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì pàgọ́ yí i ká.
6 Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ Ahimeleki, ará Hiti ati Abiṣai ọmọ Seruaya, arakunrin Joabu pé, “Ta ni yóo bá mi lọ sí ibùdó Saulu?”Abiṣai dáhùn pé, “N óo bá ọ lọ.”
7 Dafidi ati Abiṣai bá lọ sí ibùdó Saulu ní òru ọjọ́ náà, Saulu sì ń sùn ní ààrin àgọ́, ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ lẹ́bàá ìrọ̀rí rẹ̀. Abineri ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì sùn yí i ká.