Samuẹli Kinni 26:15-21 BM

15 Dafidi dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kọ́ ni alágbára jùlọ ní Israẹli? Kí ló dé tí o kò dáàbò bo ọba, oluwa rẹ? Láìpẹ́ yìí ni ẹnìkan wọ inú àgọ́ yín láti pa oluwa rẹ.

16 Ohun tí o ṣe yìí kò dára, mo fi OLUWA ṣe ẹ̀rí pé, ó yẹ kí o kú, nítorí pé o kò dáàbò bo oluwa rẹ, ẹni àmì òróró OLUWA. Níbo ni ọ̀kọ̀ ọba wà? Ibo sì ni ìgò omi tí ó wà ní ìgbèrí rẹ̀ wà pẹlu?”

17 Saulu mọ̀ pé Dafidi ni ó ń sọ̀rọ̀, ó bá bèèrè pé, “Dafidi ọmọ mi, ṣé ìwọ ni ò ń sọ̀rọ̀?”Dafidi dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, oluwa mi.

18 Kí ló dé tí o fi ń lépa èmi iranṣẹ rẹ? Kí ni mo ṣe? Kí sì ni ẹ̀ṣẹ̀ mi?

19 Oluwa mi, gbọ́ ohun tí èmi iranṣẹ rẹ fẹ́ sọ. Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni ó gbé ọ dìde sí mi, kí ó gba ẹbọ ẹ̀bẹ̀, ṣugbọn bí ó bá jẹ́ pé eniyan ni, kí ègún OLUWA wá sórí olúwarẹ̀, nítorí wọ́n lé mi jáde, kí n má baà ní ìpín ninu ilẹ̀ ìní tí OLUWA fún àwọn eniyan rẹ̀. Wọ́n ń sọ fún mi pé kí n lọ máa bọ oriṣa.

20 Má jẹ́ kí n kú sílẹ̀ àjèjì níbi tí OLUWA kò sí. Kí ló dé tí ọba Israẹli fi ń lépa èmi kékeré yìí, bí ẹni ń dọdẹ àparò lórí òkè?”

21 Saulu dáhùn pé, “Mo ti ṣe ibi, máa bọ̀ Dafidi, ọmọ mi. N kò ní ṣe ọ́ ní ibi mọ́, nítorí pé ẹ̀mí mi níye lórí lójú rẹ lónìí. Mo ti hùwà òmùgọ̀, ohun tí mo ṣe burú pupọ.”