4 ó rán amí láti rí i dájú pé Saulu wà níbẹ̀.
5 Dafidi lọ lẹsẹkẹsẹ láti rí ibi tí Saulu ati Abineri, ọmọ Neri, olórí ogun Saulu, dùbúlẹ̀ sí. Saulu wà ninu àgọ́, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì pàgọ́ yí i ká.
6 Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ Ahimeleki, ará Hiti ati Abiṣai ọmọ Seruaya, arakunrin Joabu pé, “Ta ni yóo bá mi lọ sí ibùdó Saulu?”Abiṣai dáhùn pé, “N óo bá ọ lọ.”
7 Dafidi ati Abiṣai bá lọ sí ibùdó Saulu ní òru ọjọ́ náà, Saulu sì ń sùn ní ààrin àgọ́, ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ gúnlẹ̀ lẹ́bàá ìrọ̀rí rẹ̀. Abineri ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sì sùn yí i ká.
8 Abiṣai bá sọ fún Dafidi pé, “Ọlọrun ti fi ọ̀tá rẹ lé ọ lọ́wọ́ ní òní yìí, gbà mí láàyè kí n yọ ọ̀kọ̀, kí n sì gún un ní àgúnpa lẹ́ẹ̀kanṣoṣo.”
9 Ṣugbọn Dafidi sọ fún Abiṣai pé, “O kò gbọdọ̀ ṣe é ní ibi kan, nítorí ẹni tí ó bá pa ẹni àmì òróró OLUWA yóo jẹ̀bi.
10 Níwọ̀n ìgbà tí OLUWA wà láàyè, OLUWA yóo pa á; tabi kí ọjọ́ ikú rẹ̀ pé, tabi kí ó kú lójú ogun.