13 Saulu bá sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, sọ ohun tí o rí fún mi.”Obinrin náà dáhùn pé, “Mo rí ẹbọra kan, tí ń jáde bọ̀ láti inú ilẹ̀.”
14 Saulu bèèrè pé, “Báwo ló rí?”Obinrin náà dáhùn pé, “Ọkunrin arúgbó kan ló ń bọ̀, ó sì fi aṣọ bora.”Saulu mọ̀ pé Samuẹli ni, ó sì tẹríba.
15 Samuẹli bi Saulu pé, “Kí ló dé tí o fi ń yọ mí lẹ́nu? Kí ló dé tí o fi gbé mi dìde?”Saulu dáhùn pé, “Mo wà ninu ìpọ́njú ńlá nítorí pé àwọn ará Filistia ń bá mi jagun, Ọlọrun sì ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí pé kò fún mi ní ìtọ́sọ́nà, yálà láti ẹnu wolii kan ni, tabi lójú àlá. Nítorí náà ni mo ṣe pè ọ́, pé kí o lè sọ ohun tí n óo ṣe fún mi.”
16 Samuẹli dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń bi mí, nígbà tí OLUWA ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ó sì ti di ọ̀tá rẹ?
17 OLUWA ti ṣe sí ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí ó sọ láti ẹnu mi. Ó ti gba ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ rẹ, ó sì ti fún Dafidi, aládùúgbò rẹ.
18 O ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, nítorí pé, o kò pa gbogbo àwọn ará Amaleki ati àwọn nǹkan ìní wọn run. Ìdí nìyí tí OLUWA fi ṣe àwọn nǹkan wọnyi sí ọ lónìí.
19 OLUWA yóo fa ìwọ ati Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́. Ní ọ̀la ni ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ yóo kú; OLUWA yóo sì fa àwọn ọmọ ogun Israẹli lé àwọn ará Filistia lọ́wọ́.”