6 Nígbà tí Saulu bèèrè lọ́wọ́ OLUWA ohun tí yóo ṣe, OLUWA kò dá a lóhùn yálà nípa àlá tabi nípa Urimu tabi nípasẹ̀ àwọn wolii.
7 Saulu bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ bá mi wá obinrin kan tí ó bá jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀, kí n lè lọ ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ rẹ̀.”Wọn sì sọ fún un pé, “Obinrin kan wà ní Endori tí ó jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀.”
8 Saulu pa ara dà, ó wọ aṣọ mìíràn, òun pẹlu àwọn ọkunrin meji kan lọ sọ́dọ̀ obinrin náà ní òru, Saulu sì sọ fún obinrin náà pé, “Lo ẹ̀mí abókùúsọ̀rọ̀ rẹ láti pe ẹni tí mo bá sọ fún ọ wá.”
9 Obinrin náà dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń dẹ tàkúté fún mi láti pa mí? O ṣá mọ ohun tí Saulu ọba ṣe, tí ó lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó kúrò ní Israẹli.”
10 Saulu bá búra ní orúkọ OLUWA pé, “Bí OLUWA ti ń bẹ, ibi kan kò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ nítorí èyí.”
11 Obinrin náà dáhùn pé, “Ta ni kí n pè fún ọ?”Saulu dáhùn pe, “Pe Samuẹli fún mi.”
12 Nígbà tí obinrin náà rí Samuẹli, ó kígbe lóhùn rara pé, “Kí ló dé tí o fi tàn mí? Àṣé Saulu ọba ni ọ́.”