15 Dafidi bi í léèrè pé, “Ṣé o lè mú mi lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ogun náà?”Ó dáhùn pé, “N óo mú ọ lọ, bí o bá ṣèlérí ní orúkọ Ọlọrun pé o kò ní pa mí, tabi kí o fi mí lé oluwa mi lọ́wọ́.”
16 Ó mú Dafidi lọ bá wọn.Àwọn ọmọ ogun náà fọ́n káàkiri, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń jó, nítorí ọpọlọpọ ìkógun tí wọ́n rí kó ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia ati Juda.
17 Ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, Dafidi kọlù wọ́n, ó sì pa wọ́n títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà. Kò sì sí ẹni tí ó là ninu wọn, àfi irinwo ọdọmọkunrin tí wọ́n gun ràkúnmí sá lọ.
18 Dafidi sì gba àwọn eniyan rẹ̀ pada, ati gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki náà kó, ati àwọn iyawo rẹ̀ mejeeji.
19 Kò sí ohun kan tí ó nù, Dafidi gba gbogbo àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin rẹ̀ pada, ati gbogbo nǹkan tí àwọn ará Amaleki kó.
20 Ó gba gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn pẹlu. Àwọn eniyan náà sì ń dá àwọn ẹran ọ̀sìn náà jọ níwájú Dafidi, wọ́n ń sọ pé, “Ìkógun Dafidi nìyí.”
21 Dafidi lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú pupọ, tí wọn kò lè kọjá odò, ṣugbọn tí wọ́n dúró lẹ́yìn odò Besori; àwọn náà wá pàdé Dafidi ati àwọn tí wọ́n bá a lọ. Dafidi sì kí wọn dáradára.