7 Dafidi sọ fún Abiatari alufaa, ọmọ Ahimeleki, pé kí ó mú efodu wá. Abiatari sì mú un wá.
8 Dafidi bá bèèrè lọ́wọ́ OLUWA pé, “Ṣé kí n lépa àwọn ọmọ ogun náà? Ṣé n óo bá wọn?”OLUWA sì dáhùn pé, “Lépa wọn, o óo bá wọn, o óo sì gba àwọn eniyan rẹ.”
9 Dafidi ati àwọn ẹgbẹta (600) ọmọlẹ́yìn rẹ̀, bá lọ, nígbà tí wọ́n dé odò Besori, apá kan ninu wọn dúró ní etí odò náà.
10 Dafidi ati irinwo (400) eniyan sì ń lépa wọn lọ, ṣugbọn àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú kò lè la odò náà kọjá, wọ́n sì dúró sí etí odò.
11 Àwọn ọmọlẹ́yìn Dafidi rí ọmọkunrin ará Ijipti kan ninu oko, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Dafidi, wọ́n fún un ní oúnjẹ ati omi,
12 èso ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ ati ìdì àjàrà meji. Nígbà tí ó jẹun tán, ó ní agbára nítorí pé kò tíì jẹun, kò sì mu omi fún ọjọ́ mẹta sẹ́yìn.
13 Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ta ni oluwa rẹ, níbo ni o sì ti wá?”Ó dáhùn pé, “Ará Ijipti ni mí, ẹrú ará Amaleki kan. Ọjọ́ kẹta nìyí tí oluwa mi ti fi mí sílẹ̀ níhìn-ín, nítorí pé ara mi kò dá.