Samuẹli Kinni 5:2-8 BM

2 Wọ́n gbé e lọ sí ilé Dagoni, oriṣa wọn; wọ́n sì gbé e kalẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ère oriṣa náà.

3 Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, àwọn ará ìlú Aṣidodu rí i pé ère Dagoni ti ṣubú lulẹ̀. Wọ́n bá a tí ó dojúbolẹ̀ níwájú àpótí OLUWA. Wọ́n bá gbé e dìde, wọ́n gbé e pada sí ààyè rẹ̀.

4 Nígbà tí ó tún di òwúrọ̀ kutukutu wọ́n tún bá a tí ère náà tún ti ṣubú tí ó tún ti dojú bolẹ̀ níwájú àpótí OLUWA, ati pé orí ati ọwọ́ rẹ̀ mejeeji ti gé kúrò, wọ́n wà nílẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà, ara rẹ̀ nìkan ni ó kù.

5 Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé títí di òní olónìí, àwọn babalóòṣà oriṣa Dagoni ati gbogbo àwọn tí wọ́n máa ń bọ ọ́ kò jẹ́ tẹ ẹnu ọ̀nà ilé oriṣa Dagoni tí ó wà ní ìlú Aṣidodu, dídá ni wọ́n máa ń dá a kọjá.

6 OLUWA jẹ àwọn ará ìlú Aṣidodu níyà gidigidi, ó sì dẹ́rùbà wọ́n. Ìyà tí ó fi jẹ wọ́n, ati àwọn tí wọn ń gbé agbègbè wọn ni pé gbogbo ara wọn kún fún kókó ọlọ́yún.

7 Nígbà tí àwọn ará Aṣidodu rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, wọ́n ní, “Ọlọrun Israẹli ni ó ń jẹ àwa ati Dagoni, oriṣa wa níyà. A kò lè jẹ́ kí àpótí Ọlọrun Israẹli yìí wà lọ́dọ̀ wa níhìn-ín mọ́ rárá.”

8 Wọ́n bá ranṣẹ lọ pe àwọn ọba Filistini jọ, wọ́n sì bi wọ́n pé, “Báwo ni kí á ti ṣe àpótí Ọlọrun Israẹli yìí?”Wọ́n dáhùn pé kí wọ́n gbé e lọ sí Gati; wọ́n bá gbé e lọ sibẹ.