10 Ni òun náà bá ṣubú lulẹ̀ lẹsẹkẹsẹ níwájú Peteru, ó bá kú. Àwọn géńdé bá wọlé, wọ́n rí òkú rẹ̀. Wọ́n bá gbé e jáde, wọ́n sì sin ín sí ẹ̀bá ọkọ rẹ̀.
11 Ẹ̀rù ńlá ba gbogbo ìjọ ati gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi.
12 Ọpọlọpọ iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu ni àwọn aposteli ṣe láàrin àwọn eniyan. Gbogbo wọn wà ní ìṣọ̀kan ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí wọn ń pè ní ti Solomoni.
13 Kò sí ẹni tí ó láyà ninu àwọn ìyókù láti darapọ̀ mọ́ wọn. Ọ̀rọ̀ wọn níyì lọ́dọ̀ àwọn eniyan.
14 Àwọn tí wọ́n gba Oluwa gbọ́ túbọ̀ ń darapọ̀ mọ́ wọn, lọkunrin ati lobinrin.
15 Nígbà tí ó yá, àwọn eniyan a máa gbé àwọn aláìsàn wá sí títì lórí ẹní ati lórí ibùsùn, pé kí òjìji Peteru lè ṣíji bò wọ́n nígbà tí ó bá ń kọjá.
16 Ọpọlọpọ àwọn eniyan wá láti agbègbè ìlú Jerusalẹmu, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn ati àwọn tí ẹ̀mí burúkú ń dà láàmú wá; a sì mú gbogbo wọn lára dá.