21 Nítorí Ọmọ-Eniyan ń lọ gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa rẹ̀, ṣugbọn ẹni tí yóo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ gbé! Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i.”
22 Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó fún wọn. Ó ní, “Ẹ gbà, èyí ni ara mi.”
23 Ó tún mú ife, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bá gbé e fún wọn. Gbogbo wọn mu ninu rẹ̀.
24 Ó wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí a fi dá majẹmu, ẹ̀jẹ̀ tí a ta sílẹ̀ fún ọpọlọpọ eniyan.
25 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé n kò ní mu ninu èso àjàrà mọ́ títí di ọjọ́ tí n óo mu ún ní ọ̀tun ninu ìjọba Ọlọrun.”
26 Lẹ́yìn tí wọ́n kọ orin tán, wọ́n jáde lọ sí Òkè Olifi.
27 Jesu bá sọ fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ óo pada lẹ́yìn mi, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ọwọ́ yóo tẹ olùṣọ́-aguntan, àwọn aguntan yóo bá fọ́nká,’