67 Nígbà tí ó rí Peteru tí ó ń yáná, ó tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ìwọ náà wà pẹlu Jesu ará Nasarẹti.”
68 Ṣugbọn Peteru sẹ́, ó ní, “Èmi kò mọ̀... Ohun tí ò ń sọ kò yé mi rárá!” Ó wá jáde lọ sí apá ẹnu ọ̀nà agbo-ilé. Bẹ́ẹ̀ ni àkùkọ kan bá kọ.
69 Iranṣẹbinrin náà tún bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn tí ó dúró pé, “Ọkunrin yìí wà ninu wọn!”
70 Ṣugbọn ó tún sẹ́.Nígbà tí ó ṣe díẹ̀ síi àwọn tí ó dúró sọ fún Peteru pé, “Dájúdájú, o wà ninu wọn nítorí ará Galili ni ọ́.”
71 Peteru bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣépè, ó bá ń búra pé, “N kò mọ ọkunrin tí ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí.”
72 Lẹsẹkẹsẹ, àkùkọ kọ ní ẹẹkeji. Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ ní ẹẹmeji, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta!” Orí Peteru wú, ó bá bú sẹ́kún.