1 Gbàrà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn olórí alufaa pẹlu àwọn àgbà ati àwọn amòfin ati gbogbo Ìgbìmọ̀ yòókù forí-korí, wọ́n de Jesu, wọ́n bá fà á lọ láti fi lé Pilatu lọ́wọ́ fún ìdájọ́.
2 Pilatu bi Jesu pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?”Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.”
3 Àwọn olórí alufaa ń fi ẹ̀sùn pupọ kàn án.
4 Pilatu bá tún bi í pé, “O kò sì fèsì rárá? Ìwọ kò gbọ́ bí wọ́n ti ń fi oríṣìíríṣìí ẹ̀sùn kàn ọ́ ni?”
5 Ṣugbọn Jesu kò tún dá a lóhùn rárá mọ́, èyí mú kí ẹnu ya Pilatu.
6 Ní ọdọọdún, ni àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, Pilatu a máa dá ẹlẹ́wọ̀n kan tí wọ́n bá bẹ̀bẹ̀ fún sílẹ̀.