14 Ṣugbọn Pilatu bi wọ́n pé, “Nítorí kí ni? Nǹkan burúkú wo ni ó ṣe?”Ṣugbọn wọ́n sá tún kígbe pé, “Kàn án mọ́ agbelebu!”
15 Pilatu bá dá Baraba sílẹ̀ fún wọn kí ó lè baà tẹ́ wọn lọ́rùn. Lẹ́yìn tí ó ti ní kí wọ́n na Jesu tán, ó bá fà á fún wọn láti kàn mọ́ agbelebu.
16 Àwọn ọmọ-ogun bá mú un lọ sí inú agbo-ilé tí ààfin gomina wà. Wọ́n pe gbogbo àwọn ọmọ-ogun yòókù,
17 wọ́n wọ̀ ọ́ ní aṣọ àlàárì, wọ́n wá fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n fi dé e lórí.
18 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí kí i pé, “Kabiyesi! Ọba àwọn Juu!”
19 Wọ́n ń lù ú ní igi lórí, wọ́n ń tutọ́ sí i lára, wọ́n wá ń kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ń júbà yẹ̀yẹ́.
20 Nígbà tí wọ́n ti fi ṣe ẹlẹ́yà tán, wọ́n bọ́ aṣọ àlàárì kúrò ní ara rẹ̀, wọ́n fi aṣọ tirẹ̀ wọ̀ ọ́, wọ́n bá fà á jáde láti lọ kàn án mọ́ agbelebu.