41 Àwọn wọnyi ti ń tẹ̀lé e láti ìgbà tí ó ti wà ní Galili, tí wọn ń ṣe iranṣẹ fún un. Ọpọlọpọ àwọn obinrin mìíràn wà níbẹ̀ tí wọ́n bá a gòkè wá sí Jerusalẹmu.
42-43 Ọjọ́ náà jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ tíí ṣe ọ̀sẹ̀ ku ọ̀la. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, Josẹfu ará Arimatia, ọlọ́lá kan ninu àwọn ìgbìmọ̀, wá. (Ó ń retí àkókò ìjọba Ọlọrun), ó bá fi ìgboyà tọ Pilatu lọ láti bèèrè òkú Jesu.
44 Ṣugbọn ẹnu ya Pilatu pé Jesu ti yára kú! Ó pe ọ̀gágun, ó bèèrè bí Jesu ti kú tipẹ́.
45 Nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn ọ̀gágun náà, ó yọ̀ǹda òkú Jesu fún Josẹfu.
46 Josẹfu bá ra aṣọ funfun kan, ó sọ òkú Jesu kalẹ̀, ó fi aṣọ náà wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibojì tí wọ́n gbẹ́ sí inú àpáta, lẹ́yìn náà ó yí òkúta dí ẹnu ibojì náà.
47 Maria Magidaleni ati Maria ìyá Josẹfu ń wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.