1 Lẹ́yìn tí Ọjọ́ Ìsinmi ti kọjá, Maria Magidaleni ati Maria ìyá Jakọbu ati Salomi ra òróró ìkunra, wọ́n fẹ́ lọ fi kun òkú Jesu.
2 Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, wọ́n dé ibojì bí oòrùn ti ń yọ.
3-4 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn ṣàròyé pé, “Ta ni yóo bá wa yí òkúta kúrò ní ẹnu ibojì?” Bí wọ́n ti gbé ojú sókè, wọ́n rí i pé ẹnìkan ti yí òkúta náà kúrò, bẹ́ẹ̀ ni òkúta ọ̀hún sì tóbi gan-an.
5 Nígbà tí wọ́n wo inú ibojì, wọ́n rí ọdọmọkunrin kan tí ó jókòó ní apá ọ̀tún wọn, tí ó wọ aṣọ funfun. Wọ́n bá ta gìrì.
6 Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ṣé Jesu ará Nasarẹti tí a kàn mọ́ agbelebu ni ẹ̀ ń wá? Ó ti jí dìde. Kò sí níhìn-ín. Ẹ wò ó! Ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí nìyí.
7 Ṣugbọn ẹ lọ, ẹ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati Peteru pé ó ti lọ ṣáájú yín sí Galili, níbẹ̀ ni ẹ óo gbé rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fun yín.”
8 Nígbà tí wọ́n jáde, aré ni wọ́n sá kúrò ní ibojì náà, nítorí ńṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, tí wọn ń dààmú. Wọn kò sọ ohunkohun fún ẹnikẹ́ni, nítorí ẹ̀rù ń bà wọ́n.[