14 Bí ó ti ń lọ, ó rí Lefi ọmọ Alfeu tí ó jókòó níbi tí ó ti ń gba owó-odè. Ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Lefi bá dìde, ó sì tẹ̀lé e.
15 Bí Jesu ti jókòó ní ilé Lefi, ọpọlọpọ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun, nítorí wọ́n pọ̀ tí wọn ń tẹ̀lé e.
16 Nígbà tí àwọn amòfin ninu àwọn Farisi rí i tí ó ń bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ati àwọn agbowó-odè jẹun, wọ́n bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ léèrè pé, “Kí ló dé tí ó fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”
17 Nígbà tí Jesu gbọ́, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá: èmi kò wá láti pe àwọn olódodo bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
18 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati àwọn Farisi ń gbààwẹ̀ ní àkókò kan. Àwọn kan wá, wọ́n ń bi Jesu pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi a máa gbààwẹ̀ ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tìrẹ kì í gbààwẹ̀?”
19 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ iyawo wà lọ́dọ̀ wọn, níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà pẹlu wọn, wọ́n kò lè máa gbààwẹ̀.
20 Ṣugbọn ọjọ́ ń bọ̀, tí a óo gba ọkọ iyawo kúrò lọ́dọ̀ wọn, wọn óo gbààwẹ̀ nígbà náà.