22 Kò sí ẹni tíí fi ọtí titun sinu ògbólógbòó àpò awọ. Tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí náà yóo bẹ́ àpò náà, ati ọtí ati àpò yóo bá ṣòfò. Ṣugbọn inú àpò awọ titun ni à ń fi ọtí titun sí.”
23 Ní àkókò kan ní Ọjọ́ Ìsinmi, bí Jesu ti ń la ààrin oko ọkà kọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà jẹ bí wọn tí ń lọ lọ́nà.
24 Àwọn Farisi wí fún un pé, “Wò bí wọn ti ń ṣe ohun tí kò tọ́ láti ṣe ní Ọjọ́ Ìsinmi!”
25 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò ì tíì ka ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí kò ní oúnjẹ, tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀?
26 Bí ó ti wọ ilé Ọlọrun lọ ní àkókò Abiatari Olórí Alufaa, tí ó jẹ burẹdi tí ó wà lórí tabili níwájú Oluwa, tí kò yẹ kí ẹnikẹ́ni jẹ, àfi alufaa nìkan, tí ó tún fún àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ jẹ?”
27 Ó wá wí fún wọn pé, “Lílò eniyan ni a dá Ọjọ́ Ìsinmi fún, a kò dá eniyan fún Ọjọ́ Ìsinmi.
28 Nítorí náà, Ọmọ-Eniyan ni Oluwa ohun gbogbo ati ti Ọjọ́ Ìsinmi pẹlu.”