5 Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”
6 Ṣugbọn àwọn amòfin kan jókòó níbẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kùn sinu pé,
7 “Kí ló dé tí eléyìí fi ń sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀? Ó ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ta ni lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bíkòṣe Ọlọrun nìkan?”
8 Ṣugbọn Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé wọ́n ń ro èrò báyìí ninu ọkàn wọn. Ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kùn sinu?
9 Èwo ni ó rọrùn jù: Láti wí fún arọ náà pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tabi láti wí pé, ‘Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa rìn?’
10 Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni,” ó bá wí fún arọ náà pé,
11 “Mo wí fún ọ, dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa lọ sí ilé rẹ.”