7 “Kí ló dé tí eléyìí fi ń sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀? Ó ń sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ta ni lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni bíkòṣe Ọlọrun nìkan?”
8 Ṣugbọn Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé wọ́n ń ro èrò báyìí ninu ọkàn wọn. Ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kùn sinu?
9 Èwo ni ó rọrùn jù: Láti wí fún arọ náà pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tabi láti wí pé, ‘Dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa rìn?’
10 Ṣugbọn kí ẹ lè mọ̀ pé Ọmọ-Eniyan ní àṣẹ ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ni,” ó bá wí fún arọ náà pé,
11 “Mo wí fún ọ, dìde, gbé ibùsùn rẹ, kí o máa lọ sí ilé rẹ.”
12 Ọkunrin náà bá dìde lẹsẹkẹsẹ, ó gbé ibùsùn rẹ̀, ó bá jáde lọ lójú gbogbo wọn. Ẹnu ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń yin Ọlọrun, wọ́n ní, “A kò rí èyí rí.”
13 Jesu tún jáde lọ sí ẹ̀bá òkun, gbogbo àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bá ń kọ́ wọn.