23 Jesu wá pè wọ́n sọ́dọ̀, ó fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Báwo ni Satani ti ṣe lè lé Satani jáde?
24 Bí ìjọba kan náà bá gbé ogun ti ara rẹ̀, ìjọba náà yóo parun.
25 Bí àwọn ará ilé kan náà bá ń bá ara wọn jà, ilé náà kò lè fi ìdí múlẹ̀.
26 Bí Satani bá gbógun ti ara rẹ̀, tí ó ń bá ara rẹ̀ jà, kò lè fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, a jẹ́ pé ó parí fún un.
27 “Ṣugbọn kò sí ẹnìkan tí ó lè wọ ilé alágbára kan lọ, kí ó kó dúkìá rẹ̀ láìjẹ́ pé ó kọ́ de alágbára náà mọ́lẹ̀, nígbà náà ni yóo tó lè kó ilé rẹ̀.
28 “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a óo dárí ji àwọn ọmọ eniyan, ati gbogbo ìsọkúsọ tí wọ́n lè máa sọ.
29 Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò lè ní ìdáríjì laelae, ṣugbọn ó jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ títí lae.”