9 Jesu wá bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?”Ó ní, “Ẹgbaagbeje ni mò ń jẹ́, nítorí a kò níye.”
10 Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Jesu títí pé kí ó má ṣe lé wọn jáde kúrò ní agbègbè ibẹ̀.
11 Agbo ọ̀pọ̀ ẹlẹ́dẹ̀ kan wà níbẹ̀, wọ́n ń jẹ lẹ́bàá òkè.
12 Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bẹ̀ ẹ́ pé kí ó rán wọn sí ààrin ẹlẹ́dẹ̀ náà, kí wọ́n lè wọ inú wọn.
13 Ó bá gbà bẹ́ẹ̀ fún wọn. Àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde lọ, wọ́n wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà bá tú pẹ̀ẹ́, wọ́n sáré láti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè lọ sí òkun, wọ́n bá rì sinu òkun. Wọ́n tó bí ẹgbaa (2,000).
14 Àwọn olùtọ́jú wọn bá sálọ sí àwọn ìlú ati àwọn abúlé tí ó wà yíká láti ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn eniyan bá wá fi ojú ara wọn rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀.
15 Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkunrin náà tí ó ti jẹ́ wèrè rí, tí ó ti ní ẹgbaagbeje ẹ̀mí èṣù, ó jókòó, ó wọ aṣọ, iyè rẹ̀ sì ti bọ̀ sípò. Ẹ̀rù ba àwọn eniyan tí ó rí i.