1 Àwọn Farisi ati àwọn amòfin kan tí wọ́n wá láti Jerusalẹmu péjọ sí ọ̀dọ̀ Jesu.
2 Wọ́n rí ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí ni pé, wọn kò wẹ ọwọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin.
3 (Nítorí pé àwọn Farisi ati gbogbo àwọn Juu yòókù kò jẹ́ jẹun láì wẹ ọwọ́ ní ọ̀nà tí òfin là sílẹ̀; wọ́n ń tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀ wọn.
4 Bí wọn bá ti ọjà dé, wọ́n kò jẹ́ jẹun láìjẹ́ pé wọ́n kọ́kọ́ wẹ̀. Ọpọlọpọ nǹkan mìíràn ni ó ti di àṣà wọn, gẹ́gẹ́ bíi fífọ àwo ìmumi, ìkòkò ìpọnmi ati àwọn àwo kòtò onídẹ.)
5 Àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá bi í pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kò fi tẹ̀lé àṣà ìbílẹ̀, tí wọn ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun?”