31 Ó tún jáde kúrò ní agbègbè ìlú Tire, ó la ìlú Sidoni kọjá lọ sí òkun Galili ní ọ̀nà ààrin Ìlú Mẹ́wàá.
32 Wọ́n wá gbé adití kan tí ń kólòlò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ lé e.
33 Ó bá mú un bọ́ sí apá kan, kúrò láàrin àwọn ọ̀pọ̀ eniyan, ó ti ìka rẹ̀ bọ ọkunrin náà létí, ó tutọ́, ó fi kan ahọ́n rẹ̀.
34 Ó gbé ojú sí òkè ọ̀run, ó kẹ́dùn, ó bá ní, “Efata,” ìtumọ̀ èyí tí i ṣe, “Ìwọ, ṣí.”
35 Etí ọkunrin náà bá ṣí, okùn ahọ́n rẹ̀ tú, ó bá ń sọ̀rọ̀ gaara.
36 Jesu kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má wí fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn bí ó ti ń kìlọ̀ fún wọn tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ròyìn rẹ̀ tó.