13 Solomoni ọba si fun ayaba Ṣeba ni gbogbo ifẹ rẹ̀, ohunkohun ti o bère, li aika eyiti a fi fun u lati ọwọ Solomoni ọba wá. Bẹ̃li o si yipada, o si lọ si ilu rẹ̀, on, ati awọn iranṣẹ rẹ̀.
14 Njẹ ìwọn wura ti o nde ọdọ Solomoni li ọdun kan, jẹ ọtalelẹgbẹta o le mẹfa talenti wura,
15 Laika eyi ti o ngbà lọwọ awọn ajẹlẹ ati awọn oniṣowo, ati ti gbogbo awọn ọba Arabia, ati ti awọn bãlẹ ilẹ.
16 Solomoni ọba si ṣe igba asà wura lilù: ẹgbẹta ṣekeli wura li o tán si asà kan.
17 O si ṣe ọdunrun apata wura lilù, oṣuwọn wura mẹta li o tán si apata kan: ọba si ko wọn si ile igbo Lebanoni.
18 Ọba si ṣe itẹ́ ehin-erin kan nla, o si fi wura didara julọ bò o.
19 Itẹ́ na ni atẹgùn mẹfa, oke itẹ́ na yi okiribiti lẹhin: irọpá si wà niha kini ati ekeji ni ibi ijoko na, kiniun meji si duro lẹba na.