1. A. Ọba 16 YCE

1 O si ṣe, ọ̀rọ Oluwa tọ Jehu, ọmọ Hanani wá, si Baaṣa wipe,

2 Bi o ti ṣepe mo gbé ọ ga lati inu ẽkuru wá, ti mo si ṣe ọ li olori Israeli, enia mi; iwọ si rìn li ọ̀na Jeroboamu, iwọ si ti mu ki Israeli enia mi ki o ṣẹ̀, lati fi ẹ̀ṣẹ wọn mu mi binu;

3 Kiyesi i, emi o mu iran Baaṣa, ati iran ile rẹ̀ kuro; emi o si ṣe ile rẹ̀ bi ile Jeroboamu, ọmọ Nebati.

4 Ẹni Baaṣa ti o ba kú ni ilu li awọn ajá yio jẹ; ati ẹni rẹ̀ ti o kú ni oko li ẹiyẹ oju-ọrun o jẹ.

5 Ati iyokù iṣe Baaṣa, ati ohun ti o ṣe, ati agbara rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

6 Baaṣa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Tirsa: Ela, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

7 Ati pẹlu nipa ọwọ́ Jehu woli, ọmọ Hanani, li ọ̀rọ Oluwa de si Baaṣa, ati si ile rẹ̀, ani nitori gbogbo ibi ti o ṣe niwaju Oluwa, ni fifi iṣẹ ọwọ́ rẹ̀ mu u binu, ati wiwà bi ile Jeroboamu, ati nitori ti o pa a.

Ela, Ọba Israẹli

8 Li ọdun kẹrindilọgbọn Asa, ọba Juda, ni Ela, ọmọ Baaṣa, bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Tirsa li ọdun meji.

9 Ati iranṣẹ rẹ̀ Simri, olori idaji kẹkẹ́ rẹ̀, dìtẹ rẹ̀, nigbati o ti wà ni Tirsa, o si mu amupara ni ile Arsa, iriju ile rẹ̀ ni Tirsa.

10 Simri si wọle o si kọlù u, o si pa a, li ọdun kẹtadilọgbọn Asa, ọba Juda, o si jọba ni ipò rẹ̀.

11 O si ṣe, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, bi o ti joko li ori itẹ rẹ̀, o lù gbogbo ile Baaṣa pa: kò kù ọmọde ọkunrin kan silẹ, ati awọn ibatan rẹ̀ ati awọn ọrẹ́ rẹ̀.

12 Bayi ni Simri pa gbogbo ile Baaṣa run, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ si Baaṣa nipa ọwọ́ Jehu woli,

13 Nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ Baaṣa, ati Ela, ọmọ rẹ̀, nipa eyiti nwọn ṣẹ̀, ati nipa eyiti nwọn mu Israeli ṣẹ̀, ni fifi ohun-asán wọn wọnnì mu ki Oluwa, Ọlọrun Israeli binu.

14 Ati iyokù iṣe Ela, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

Simiri, Ọba Israẹli

15 Li ọdun kẹtadilọgbọn Asa, ọba Juda, ni Simri jọba ijọ meje ni Tirsa. Awọn enia si do tì Gibbetoni, ti awọn ara Filistia.

16 Awọn enia ti o dotì gbọ́ wipe, Simri ditẹ̀ o si ti pa ọba pẹlu: nitorina gbogbo Israeli fi Omri, olori ogun, jẹ ọba lori Israeli li ọjọ na ni ibudo.

17 Omri si goke lati Gibbetoni lọ, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, nwọn si do tì Tirsa.

18 O si ṣe, nigbati Simri mọ̀ pe a gba ilu, o wọ inu ãfin ile ọba lọ, o si tẹ iná bọ ile ọba lori ara rẹ̀, o si kú.

19 Nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀ wọnni ti o da, ni ṣiṣe buburu niwaju Oluwa, ni rirìn li ọ̀na Jeroboamu ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da, lati mu ki Israeli ki o ṣẹ̀.

20 Ati iyokù iṣe Simri, ati ọtẹ rẹ̀ ti o dì, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

Omiri, Ọba Israẹli

21 Nigbana li awọn enia Israeli da meji; apakan awọn enia ntọ̀ Tibni, ọmọ Ginati lẹhin, lati fi i jọba, apakan si ntọ̀ Omri lẹhin.

22 Ṣugbọn awọn enia ti ntọ̀ Omri lẹhin bori awọn ti ntọ̀ Tibni, ọmọ Ginati lẹhin: bẹ̃ni Tibni kú, Omri si jọba.

23 Li ọdun kọkanlelọgbọn Asa, ọba Juda, ni Omri bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli fun ọdun mejila: ọdun mẹfa li o jọba ni Tirsa.

24 O si rà oke Samaria lọwọ Semeri ni talenti meji fadaka, o si tẹdo lori oke na, o si pe orukọ ilu na ti o tẹ̀do ni Samaria nipa orukọ Semeri, oluwa oke Samaria.

25 Ṣugbọn Omri ṣe buburu li oju Oluwa, o si ṣe buburu jù gbogbo awọn ti o wà ṣãju rẹ̀.

26 Nitori ti o rìn ni gbogbo ọ̀na Jeroboamu, ọmọ Nebati, ati ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, eyiti o mu Israeli ṣẹ̀, lati fi ohun-asán wọn wọnni mu Oluwa, Ọlọrun Israeli binu.

27 Ati iyokù iṣe Omri ti o ṣe, ati agbara rẹ̀ ti o fi hàn, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

28 Omri si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni Samaria: Ahabu ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Ahabu Ọba Israẹli

29 Ati li ọdun kejidilogoji Asa, ọba Juda, ni Ahabu, ọmọ Omri, bẹ̀rẹ si jọba lori Israeli: Ahabu, ọmọ Omri, si jọba lori Israeli ni Samaria li ọdun mejilelogun,

30 Ahabu, ọmọ Omri, si ṣe buburu li oju Oluwa jù gbogbo awọn ti o wà ṣaju rẹ̀ lọ.

31 O si ṣe, bi ẹnipe o ṣe ohun kekere fun u lati ma rìn ninu ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ọmọ Nebati, o si mu Jesebeli, ọmọbinrin Etbaali, ọba awọn ara Sidoni li aya, o si lọ, o si sin Baali, o si bọ ọ,

32 O si tẹ pẹpẹ kan fun Baali ninu ile Baali, ti o kọ́ ni Samaria.

33 Ahabu si ṣe ere oriṣa kan; Ahabu si ṣe jù gbogbo awọn ọba Israeli lọ, ti o wà ṣaju rẹ̀, lati mu ki Oluwa Ọlọrun Israeli binu.

34 Li ọjọ rẹ̀ ni Hieli, ara Beteli, kọ́ Jeriko: o fi ipilẹ rẹ̀ le ilẹ ni Abiramu, akọbi rẹ̀, o si gbé awọn ilẹkun ibode rẹ̀ kọ́ ni Segubu abikẹhin rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti ipa Joṣua, ọmọ Nuni sọ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22