1. A. Ọba 8 YCE

Wọ́n gbé àpótí ẹ̀rí wá sí inú Tẹmpili

1 NIGBANA ni Solomoni papejọ awọn agba Israeli, ati gbogbo awọn olori awọn ẹ̀ya, awọn olori awọn baba awọn ọmọ Israeli, si ọdọ Solomoni ọba ni Jerusalemu, ki nwọn ki o lè gbe apoti-ẹri majẹmu Oluwa wá lati ilu Dafidi, ti iṣe Sioni.

2 Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si pe ara wọn jọ si ọdọ Solomoni ọba ni ajọ ọdun ni oṣu Etanimu, ti iṣe oṣu keje.

3 Gbogbo awọn agbàgba Israeli si wá, awọn alufa si gbe apoti-ẹri.

4 Nwọn si gbe apoti-ẹ̀ri Oluwa wá soke, ati agọ ajọ enia, ati gbogbo ohun-elo mimọ́ ti o wà ninu agọ ani nkan wọnni ni awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi gbe goke wá.

5 Ati Solomoni ọba, ati gbogbo ijọ enia Israeli ti o pejọ si ọdọ rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀ niwaju apoti-ẹri, nwọn nfi agutan ati malu ti a kò le mọ̀ iye, ti a kò le kà fun ọ̀pọlọpọ rubọ.

6 Awọn alufa si gbe apoti-ẹri majẹmu Oluwa wá si ipò rẹ̀ sinu ibi-idahùn ile na, ni ibi mimọ́-julọ labẹ iyẹ awọn kerubu.

7 Nitori awọn kerubu nà iyẹ wọn mejeji si ibi apoti-ẹri, awọn kerubu na si bò apọti-ẹri ati awọn ọpá rẹ̀ lati oke wá.

8 Nwọn si fa awọn ọpá na jade tobẹ̃ ti a nfi ri ori awọn ọpá na lati ibi mimọ́ niwaju ibi-idahùn, a kò si ri wọn lode: nibẹ ni awọn si wà titi di oni yi.

9 Kò si nkankan ninu apoti-ẹri bikoṣe tabili okuta meji, ti Mose ti fi si ibẹ ni Horebu nigbati Oluwa ba awọn ọmọ Israeli dá majẹmu, nigbati nwọn ti ilẹ Egipti jade.

10 O si ṣe, nigbati awọn alufa jade lati ibi mimọ́ wá, awọsanma si kún ile Oluwa.

11 Awọn alufa kò si le duro ṣiṣẹ nitori awọsanma na: nitori ogo Oluwa kún ile Oluwa.

12 Nigbana ni Solomoni sọ pe: Oluwa ti wi pe, on o mã gbe inu okùnkun biribiri.

13 Nitõtọ emi ti kọ́ ile kan fun ọ lati mã gbe inu rẹ̀, ibukojo kan fun ọ lati mã gbe inu rẹ̀ titi lai.

Ọ̀rọ̀ tí Solomoni bá àwọn eniyan sọ

14 Ọba si yi oju rẹ̀, o si fi ibukún fun gbogbo ijọ enia Israeli: gbogbo ijọ enia Israeli si dide duro;

15 O si wipe, Ibukún ni fun Oluwa, Ọlọrun Israeli, ti o fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ fun Dafidi, baba mi, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ mu u ṣẹ, wipe,

16 Lati ọjọ ti emi ti mu Israeli, awọn enia mi jade kuro ni Egipti, emi kò yàn ilu kan ninu gbogbo ẹyà Israeli lati kọ́ ile kan, ki orukọ mi ki o le mã gbe inu rẹ̀: ṣugbọn emi yàn Dafidi ṣe olori Israeli, awọn enia mi.

17 O si wà li ọkàn Dafidi, baba mi, lati kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun Israeli.

18 Oluwa si wi fun Dafidi baba mi pe, Bi o tijẹpe o wà li ọkàn rẹ lati kọ́ ile kan fun orukọ mi, iwọ ṣe rere ti o fi wà li ọkàn rẹ.

19 Ṣibẹ̀ iwọ kì yio kọ́ ile na, ṣugbọn ọmọ rẹ ti yio ti inu rẹ jade, on ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi.

20 Oluwa si mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti sọ, emi si dide ni ipò Dafidi, baba mi, mo si joko lori itẹ́ Israeli, gẹgẹ bi Oluwa ti sọ, emi si kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun Israeli.

21 Emi si ti ṣe àye kan nibẹ̀ fun apoti-ẹri, ninu eyiti majẹmu Oluwa gbe wà, ti o ti ba awọn baba wa dá, nigbati o mu wọn jade lati ilẹ Egipti wá.

Adura Solomoni

22 Solomoni si duro niwaju pẹpẹ Oluwa, loju gbogbo ijọ enia Israeli, o si nà ọwọ́ rẹ̀ mejeji soke ọrun:

23 O si wipe, Oluwa Ọlọrun Israeli, kò si Ọlọrun ti o dabi rẹ loke ọrun, tabi ni isalẹ ilẹ, ti ipa majẹmu ati ãnu mọ pẹlu awọn iranṣẹ rẹ ti nfi gbogbo ọkàn wọn rin niwaju rẹ:

24 Ẹniti o ti ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa ohun ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ: iwọ fi ẹnu rẹ sọ pẹlu, o si ti fi ọwọ́ rẹ mu u ṣẹ, gẹgẹ bi o ti ri loni.

25 Njẹ nisisiyi, Oluwa Ọlọrun Israeli, ba iranṣẹ rẹ Dafidi, baba mi pa ohun ti iwọ ti ṣe ileri fun u mọ́ wipe, A kì yio fẹ ọkunrin kan kù li oju mi lati joko lori itẹ Israeli; kiki bi awọn ọmọ rẹ ba le kiyesi ọ̀na wọn, ki nwọn ki o mã rìn niwaju mi gẹgẹ bi iwọ ti rìn niwaju mi.

26 Njẹ nisisiyi, Ọlọrun Israeli, jẹ ki a mu ọ̀rọ rẹ ṣẹ, emi bẹ̀ ọ, ti iwọ ti sọ fun iranṣẹ rẹ, Dafidi baba mi.

27 Ṣugbọn nitõtọ Ọlọrun yio ha mã gbe aiye bi? wò o, ọrun ati ọrun awọn ọrun kò le gbà ọ; ambọ̀sì ile yi ti mo kọ́?

28 Sibẹ̀ iwọ ṣe afiyèsi adura iranṣẹ rẹ, ati si ẹbẹ rẹ̀, Oluwa Ọlọrun mi, lati tẹtisilẹ si ẹkun ati si adura, ti iranṣẹ rẹ ngbà niwaju rẹ loni:

29 Ki oju rẹ lè ṣi si ile yi li ọsan ati li oru, ani si ibi ti iwọ ti wipe: Orukọ mi yio wà nibẹ: ki iwọ ki o lè tẹtisilẹ si adura ti iranṣẹ rẹ yio gbà si ibi yi.

30 Ki o si tẹtisilẹ si ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ ati ti Israeli, enia rẹ, ti nwọn o gbadura siha ibi yi: ki o si gbọ́ li ọrun, ibugbe rẹ! gbọ́, ki o si darijì.

31 Bi ẹnikan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji rẹ̀, ti a si fi ibura le e lati mu u bura, bi ibura na ba si de iwaju pẹpẹ rẹ ni ile yi:

32 Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si ṣe, ki o si dajọ awọn iranṣẹ rẹ, ni didẹbi fun enia buburu, lati mu ọ̀na rẹ̀ wá si ori rẹ̀; ati ni didare fun olõtọ, lati fun u gẹgẹ bi ododo rẹ̀.

33 Nigbati a ba lù Israeli, enia rẹ bòlẹ niwaju awọn ọ̀ta, nitoriti nwọn dẹṣẹ si ọ, ti nwọn ba si yipada si ọ, ti nwọn si jẹwọ orukọ rẹ, ti nwọn si gbadura, ti nwọn si bẹ̀bẹ lọdọ rẹ ni ile yi:

34 Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ Israeli, enia rẹ jì, ki o si mu wọn pada wá si ilẹ ti iwọ ti fi fun awọn baba wọn.

35 Nigbati a ba sé ọrun mọ, ti kò si òjo, nitoriti nwọn ti dẹṣẹ si ọ: bi nwọn ba gbadura si iha ibi yi, ti nwọn si jẹwọ orukọ rẹ, bi nwọn ba si yipada kuro ninu ẹ̀ṣẹ wọn, nigbati iwọ ba pọ́n wọn li oju.

36 Nigbana ni ki o gbọ́ li ọrun, ki o si dari ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ jì, ati ti Israeli, enia rẹ, nigbati o kọ́ wọn li ọ̀na rere ninu eyiti nwọn iba mã rin, ki o si rọ̀ òjo si ilẹ rẹ, ti iwọ ti fi fun enia rẹ ni ilẹ-ini.

37 Bi iyàn ba mu ni ilẹ, bi ajakalẹ-arùn ni, tabi ìrẹdanu, tabi bibu, tabi bi ẽṣu tabi bi kòkorò ti njẹrun ba wà; bi ọtá wọn ba dó tì wọn ni ilẹ ilu wọn; ajakalẹ-arùn gbogbo, arùn-ki-arun gbogbo.

38 Adura ki adura, ati ẹ̀bẹ ki ẹ̀bẹ, ti a ba ti ọdọ ẹnikan tabi lati ọdọ gbogbo Israeli, enia rẹ gbà, ti olukuluku yio mọ̀ ibanujẹ ọkàn ara rẹ̀, bi o ba si tẹ́ ọwọ́ rẹ̀ mejeji si iha ile yi!

39 Nigbana ni ki iwọ ki o gbọ́ li ọrun, ibugbe rẹ, ki o si darijì, ki o si ṣe ki o si fun olukulùku enia gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀, ọkàn ẹniti iwọ mọ̀; nitoriti iwọ, iwọ nikanṣoṣo li o mọ̀ ọkàn gbogbo awọn ọmọ enia;

40 Ki nwọn ki o lè mã bẹ̀ru rẹ ni gbogbo ọjọ ti nwọn wà ni ilẹ ti iwọ fi fun awọn baba wa.

41 Pẹlupẹlu, niti alejò, ti kì iṣe ti inu Israeli enia rẹ, ṣugbọn ti o ti ilẹ okerè jade wá nitori orukọ rẹ.

42 Nitoriti nwọn o gbọ́ orukọ nla rẹ, ati ọwọ́ agbára rẹ, ati ninà apa rẹ; nigbati on o wá, ti yio si gbadura si iha ile yi;

43 Iwọ gbọ́ li ọrun, ibùgbe rẹ, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti alejò na yio ke pè ọ si: ki gbogbo aiye ki o lè mọ̀ orukọ rẹ, ki nwọn ki o lè mã bẹ̀ru rẹ, gẹgẹ bi Israeli, enia rẹ, ki nwọn ki o si lè mọ̀ pe: orukọ rẹ li a fi npè ile yi ti mo kọ́.

44 Bi enia rẹ ba jade lọ si ogun si ọtá wọn, li ọ̀na ti iwọ o rán wọn, bi nwọn ba si gbadura si Oluwa siha ilu ti iwọ ti yàn, ati siha ile ti mo kọ́ fun orukọ rẹ.

45 Nigbana ni ki o gbọ́ adura wọn, ati ẹ̀bẹ wọn li ọrun, ki o si mu ọràn wọn duro.

46 Bi nwọn ba ṣẹ̀ si ọ, nitoriti kò si enia kan ti kì iṣẹ̀, bi iwọ ba si binu si wọn, ti o si fi wọn le ọwọ́ ọta, tobẹ̃ ti a si kó wọn lọ ni igbèkun si ilẹ ọta, jijìna tabi nitosi;

47 Bi nwọn ba rò inu ara wọn wò ni ilẹ nibiti a gbe kó wọn ni igbèkun lọ, ti nwọn ba si ronupiwàda, ti nwọn ba si bẹ̀ ọ ni ilẹ awọn ti o kó wọn ni igbèkun lọ, wipe, Awa ti dẹṣẹ, awa ti ṣe ohun ti kò tọ, awa ti ṣe buburu;

48 Bi nwọn ba si fi gbogbo àiya ati gbogbo ọkàn wọn yipada si ọ ni ilẹ awọn ọta wọn, ti o kó wọn ni igbèkun lọ, ti nwọn si gbadura si ọ siha ilẹ wọn, ti iwọ ti fi fun awọn baba wọn, ilu ti iwọ ti yàn, ati ile ti emi kọ́ fun orukọ rẹ:

49 Nigbana ni ki iwọ ki o gbọ́ adura wọn ati ẹ̀bẹ wọn li ọrun ibugbe rẹ, ki o si mu ọ̀ran wọn duro:

50 Ki o si darijì awọn enia rẹ ti o ti dẹṣẹ si ọ, ati gbogbo irekọja wọn ninu eyiti nwọn ṣẹ̀ si ọ, ki o si fun wọn ni ãnu niwaju awọn ti o kó wọn ni igbèkun lọ, ki nwọn ki o le ṣãnu fun wọn.

51 Nitori enia rẹ ati ini rẹ ni nwọn, ti iwọ mu ti Egipti jade wá, lati inu ileru irin:

52 Ki oju rẹ ki o le ṣi si ẹ̀bẹ iranṣẹ rẹ, ati si ẹ̀bẹ Israeli enia rẹ, lati tẹtisilẹ si wọn ninu ohun gbogbo ti nwọn o ke pè ọ si.

53 Nitoriti iwọ ti yà wọn kuro ninu gbogbo orilẹ-ède aiye, lati mã jẹ ini rẹ, bi iwọ ti sọ lati ọwọ Mose iranṣẹ rẹ, nigbati iwọ mu awọn baba wa ti Egipti jade wá, Oluwa Ọlọrun.

Adura Ìparí

54 O si ṣe, bi Solomoni ti pari gbigbà gbogbo adura ati ẹ̀bẹ yi si Oluwa, o dide kuro lori ikunlẹ ni ẽkún rẹ̀ niwaju pẹpẹ Oluwa pẹlu titẹ́ ọwọ rẹ̀ si oke ọrun.

55 O si dide duro, o si fi ohùn rara sure fun gbogbo ijọ enia Israeli wipe,

56 Ibukún ni fun Oluwa ti o ti fi isimi fun Israeli enia rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ti ṣe ileri: kò kù ọ̀rọ kan ninu gbogbo ileri rere rẹ̀ ti o ti ṣe lati ọwọ Mose, iranṣẹ rẹ̀ wá.

57 Oluwa Ọlọrun wa ki o wà pẹlu wa, bi o ti wà pẹlu awọn baba wa: ki o má fi wa silẹ, ki o má si ṣe kọ̀ wa silẹ;

58 Ṣugbọn ki o fa ọkàn wa si ọdọ ara rẹ̀, lati ma rin ninu gbogbo ọ̀na rẹ̀, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, ti o ti paṣẹ fun awọn baba wa.

59 Ki o si jẹ ki ọ̀rọ mi wọnyi, ti mo fi bẹ̀bẹ niwaju Oluwa, ki o wà nitosi, Oluwa Ọlọrun wa, li ọsan ati li oru, ki o le mu ọ̀ran iranṣẹ rẹ duro, ati ọ̀ran ojojumọ ti Israeli, enia rẹ̀.

60 Ki gbogbo enia aiye le mọ̀ pe, Oluwa on li Ọlọrun, kò si ẹlomiran.

61 Nitorina, ẹ jẹ ki aìya nyin ki o pé pẹlu Oluwa Ọlọrun wa, lati mã rìn ninu aṣẹ rẹ̀, ati lati pa ofin rẹ̀ mọ́, bi ti oni yi.

Yíya ilé OLUWA sí mímọ́

62 Ati ọba, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, ru ẹbọ niwaju Oluwa.

63 Solomoni si ru ẹbọ ọrẹ-alafia, ti o ru si Oluwa, ẹgbã-mọkanla malu, ati ọkẹ mẹfa àgutan. Bẹ̃ni ọba ati gbogbo awọn ọmọ Israeli yà ile Oluwa si mimọ́.

64 Li ọ̀jọ na ni ọba yà agbàla ãrin ti mbẹ niwaju ile Oluwa si mimọ́: nitori nibẹ ni o ru ẹbọ ọrẹ-sisun, ati ọrẹ-onjẹ, ati ẹbọ-ọpẹ: nitori pẹpẹ idẹ ti mbẹ niwaju Oluwa kere jù lati gba ọrẹ-sisun ati ọrẹ-ọnjẹ, ati ọ̀ra ẹbọ-ọpẹ.

65 Ati li àkoko na, Solomoni papejọ kan, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, ajọ nla-nlã ni, lati iwọ Hamati titi de odò Egipti, niwaju Oluwa Ọlọrun wa, ijọ meje on ijọ meje, ani ijọ mẹrinla.

66 Li ọjọ kẹjọ o rán awọn enia na lọ: nwọn si sure fun ọba, nwọn si lọ sinu agọ wọn pẹlu ayọ̀ ati inu-didun, nitori gbogbo ore ti Oluwa ti ṣe fun Dafidi, iranṣẹ rẹ̀, ati fun Israeli, enia rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22