1. A. Ọba 22 YCE

Wolii Mikaaya Kìlọ̀ fún Ahabu

1 ỌDUN mẹta si rekọja laisi ogun lãrin Siria ati lãrin Israeli.

2 O si ṣe li ọdun kẹta, Jehoṣafati, ọba Juda sọkalẹ tọ ọba Israeli wá.

3 Ọba Israeli si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹnyin ha mọ̀ pe, tiwa ni Ramoti-Gileadi, awa si dakẹ, a kò si gbà a kuro lọwọ ọba Siria?

4 O si wi fun Jehoṣafati pe, Iwọ o ha bá mi lọ si ogun Ramoti-Gileadi bi? Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Emi bi iwọ, enia mi bi enia rẹ, ẹṣin mi bi ẹṣin rẹ.

5 Jehoṣafati si wi fun ọba Israeli pe, Mo bẹ̀ ọ, bère ọ̀rọ Oluwa li oni yi.

6 Nigbana ni ọba Israeli kó awọn woli jọ, bi irinwo ọkunrin, o si wi fun wọn pe, Ki emi ki o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki emi ki o jọwọ rẹ̀? Nwọn si wipe, Goke lọ: nitoriti Oluwa yio fi i le ọba lọwọ.

7 Jehoṣafati si wipe, Kò si woli Oluwa kan nihin pẹlu, ti awa iba bère lọwọ rẹ̀?

8 Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, ọkunrin kan Mikaiah, ọmọ Imla, mbẹ sibẹ, lọdọ ẹniti awa iba bère lọwọ Oluwa: ṣugbọn emi korira rẹ̀, nitori kì isọ asọtẹlẹ ire si mi, bikoṣe ibi. Jehoṣafati si wipe, Ki ọba má sọ bẹ̃.

9 Ọba Israeli si pè iwẹfa kan, o si wipe, Mu ki Mikaiah, ọmọ Imla, ki o yara wá.

10 Ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda joko olukulùku lori itẹ́ rẹ̀, nwọn wọ̀ aṣọ igunwa wọn ni ita ẹnu-bode Samaria, gbogbo awọn woli na si nsọtẹlẹ niwaju wọn.

11 Sedekiah, ọmọ Kenaana si ṣe iwo irin fun ara rẹ̀, o si wipe: Bayi li Oluwa wi, Wọnyi ni iwọ o fi kàn ara Siria titi iwọ o fi run wọn.

12 Gbogbo awọn woli si nsọtẹlẹ bẹ̃ wipe: Goke lọ si Ramoti-Gileadi, ki o si ṣe rere: nitoriti Oluwa yio fi i le ọba lọwọ.

13 Onṣẹ ti o lọ ipè Mikaiah wi fun u pe, Kiyesi i nisisiyi, ẹnu kanna ni ọ̀rọ awọn woli fi jẹ rere fun ọba: emi bẹ̀ ọ, jẹ ki ọ̀rọ rẹ ki o dabi ọ̀rọ ọkan ninu wọn, ki o si sọ rere.

14 Mikaiah si wipe, Bi Oluwa ti wà, ohun ti Oluwa ba sọ fun mi li emi o sọ.

15 Bẹ̃ni o de ọdọ ọba. Ọba si wi fun u pe, Mikaiah, ki awa o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki a jọwọ rẹ̀? O si da a lohùn pe, Lọ, ki o si ṣe rere: nitori Oluwa yio fi i le ọba lọwọ.

16 Ọba si wi fun u pe, Igba melo li emi o fi ọ bu pe, ki iwọ ki o máṣe sọ ohun kan fun mi bikoṣe otitọ li orukọ Oluwa?

17 On si wipe, Mo ri gbogbo Israeli tukakiri lori awọn oke bi agutan ti kò ni oluṣọ: Oluwa si wipe, Awọn wọnyi kò ni oluwa, jẹ ki nwọn ki o pada olukuluku si ile rẹ̀ li alafia.

18 Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi kò sọ fun ọ, pe on kì o fọ̀ ire si mi, bikoṣe ibi?

19 On si wipe, Nitorina, iwọ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Mo ri Oluwa joko lori itẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun-ọrun duro li apa ọtun ati li apa òsi rẹ̀.

20 Oluwa si wipe, Tani yio tàn Ahabu, ki o le goke lọ, ki o si le ṣubu ni Ramoti-Gileadi? Ẹnikan si wi bayi, ẹlomiran si sọ miran.

21 Ẹmi kan si jade wá, o si duro niwaju Oluwa, o si wipe, Emi o tàn a.

22 Oluwa si wi fun u pe, Bawo? O si wipe, Emi o jade lọ, emi o si di ẹmi-eke li ẹnu gbogbo awọn woli rẹ̀. On si wipe, Iwọ o tàn a, iwọ o si bori pẹlu: jade lọ, ki o si ṣe bẹ̃.

23 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, Oluwa ti fi ẹmi-eke si ẹnu gbogbo awọn woli rẹ wọnyi, Oluwa si ti sọ ibi si ọ.

24 Nigbana ni Sedekiah, ọmọ Kenaana sunmọ ọ, o si lu Mikaiah li ẹ̀rẹkẹ, o si wipe, Ọ̀na wo li ẹmi Oluwa gbà lọ kuro lọdọ mi lati ba ọ sọ̀rọ?

25 Mikaiah si wipe, Kiyesi i, iwọ o ri i li ọjọ na, nigbati iwọ o lọ lati inu iyẹwu de iyẹwu lati fi ara rẹ pamọ.

26 Ọba Israeli si wipe, Mu Mikaiah, ki ẹ si mu u pada sọdọ Amoni, olori ilu, ati sọdọ Joaṣi, ọmọ ọba:

27 Ki ẹ si wipe, Bayi li ọba wi: Ẹ fi eleyi sinu tubu, ki ẹ si fi onjẹ ipọnju ati omi ipọnju bọ́ ọ, titi emi o fi pada bọ̀ li alafia.

28 Mikaiah si wipe, Ni pipada bi iwọ ba pada bọ̀ li alafia, njẹ Oluwa kò ti ipa mi sọ̀rọ. O si wipe, Ẹ gbọ́, ẹnyin enia gbogbo!

Ikú Ahabu

29 Bẹ̃ni ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda, goke lọ si Ramoti-Gileadi.

30 Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi o pa aṣọ dà, emi o si lọ si oju ija; ṣugbọn iwọ gbé aṣọ igunwà rẹ wọ̀. Ọba Israeli si pa aṣọ dà, o si lọ si oju ijà.

31 Ṣugbọn ọba Siria paṣẹ fun awọn olori-kẹkẹ́ rẹ̀, mejilelọgbọn, ti o ni aṣẹ lori kẹkẹ́ rẹ̀ wipe, Máṣe ba ẹni-kekere tabi ẹni-nla jà, bikoṣe ọba Israeli nikan.

32 O si ṣe, bi awọn olori-kẹkẹ́ ti ri Jehoṣafati, nwọn si wipe, ọba Israeli li eyi. Nwọn si yà sapakan lati ba a jà: Jehoṣafati si kigbe.

33 O si ṣe, nigbati awọn olori kẹkẹ́ woye pe, kì iṣe ọba Israeli li eyi, nwọn si pada kuro lẹhin rẹ̀.

34 Ọkunrin kan si fà ọrun rẹ̀ laipete, o si ta ọba Israeli lãrin ipade ẹwu-irin; nitorina li o ṣe wi fun olutọju-kẹkẹ́ rẹ̀ pe, Yi ọwọ́ rẹ dà, ki o si mu mi jade kuro ninu ogun; nitoriti emi gbọgbẹ.

35 Ogun na si le li ọjọ na: a si dá ọba duro ninu kẹkẹ́ kọju si awọn ara Siria, o si kú li aṣalẹ, ẹ̀jẹ si ṣàn jade lati inu ọgbẹ na si ãrin kẹkẹ́ na.

36 A si kede la ibudo já li akokò iwọ̀ õrun wipe, Olukuluku si ilu rẹ̀, ati olukuluku si ilẹ rẹ̀.

37 Bẹ̃ni ọba kú, a si gbe e wá si Samaria; nwọn si sin ọba ni Samaria.

38 Ẹnikan si wẹ kẹkẹ́ na ni adagun Samaria, awọn ajá si la ẹ̀jẹ rẹ̀; awọn àgbere si wẹ ara wọn ninu rẹ̀ gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti o sọ,

39 Ati iyokù iṣe Ahabu, ati gbogbo eyi ti o ṣe, ati ile ehin-erin ti o kọ́, ati gbogbo ilu ti o tẹ̀do, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?

40 Ahabu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; Ahasiah, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Jehoṣafati, Ọba Juda

41 Jehoṣafati, ọmọ Asa, si bẹ̀rẹ si ijọba lori Juda li ọdun kẹrin Ahabu, ọba Israeli.

42 Jehoṣafati si to ẹni ọdun marundilogoji nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba ọdun mẹ̃dọgbọn ni Jerusalẹmu. Orukọ iya rẹ̀ ni Asuba ọmọbinrin Ṣilhi.

43 O si rin ni gbogbo ọ̀na Asa baba rẹ̀; kò yipada kuro ninu rẹ̀, o nṣe eyiti o tọ li oju Oluwa: kiki a kò mu awọn ibi giga kuro; awọn enia si nrú ẹbọ, nwọn si nsun turari sibẹ̀ ni ibi giga wọnni.

44 Jehoṣafati si wà li alafia pẹlu ọba Israeli.

45 Ati iyokù iṣe Jehoṣafati ati iṣe agbara rẹ̀ ti o ṣe, ati bi o ti jagun si, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

46 Iyokù awọn ti nhuwà panṣaga ti o kù li ọjọ Asa baba rẹ̀, li o parun kuro ni ilẹ na.

47 Nigbana kò si ọba ni Edomu: adelé kan li ọba.

48 Jehoṣafati kàn ọkọ̀ Tarṣiṣi lati lọ si Ofiri fun wura; ṣugbọn nwọn kò lọ: nitori awọn ọkọ̀ na fọ́ ni Esion-Geberi.

49 Nigbana ni Ahasiah, ọmọ Ahabu, wi fun Jehoṣafati pe, Jẹ ki awọn iranṣẹ mi ba awọn iranṣẹ rẹ lọ ninu ọkọ̀. Ṣugbọn Jehoṣafati kọ̀.

50 Jehoṣafati si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi, baba rẹ̀: Jehoramu, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.

Ahasaya, Ọba Israẹli

51 Ahasiah, ọmọ Ahabu, bẹ̀rẹ si ijọba lori Israeli ni Samaria li ọdun kẹtadilogun Jehoṣafati, ọba Juda, o si jọba li ọdun meji lori Israeli.

52 O si ṣe ibi niwaju Oluwa, o si rìn li ọ̀na baba rẹ̀, ati li ọ̀na iya rẹ̀, ati li ọ̀na Jeroboamu, ọmọ Nebati, ti o mu Israeli dẹ̀ṣẹ:

53 Nitoriti o sin Baali, o si mbọ ọ, o si mu Oluwa, Ọlọrun Israeli binu, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ ti ṣe.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22