1. A. Ọba 11 YCE

Solomoni Yipada Kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun

1 ṢUGBỌN Solomoni ọba fẹràn ọ̀pọ ajeji obinrin, pẹlu ọmọbinrin Farao, awọn obinrin ara Moabu, ti Ammoni, ti Edomu, ti Sidoni ati ti awọn ọmọ Hitti.

2 Awọn orilẹ-ède ti Oluwa wi fun awọn ọmọ-Israeli pe, Ẹnyin kò gbọdọ wọle tọ̀ wọn, bẹ̃ni awọn kò gbọdọ wọle tọ̀ nyin: nitõtọ nwọn o yi nyin li ọkàn pada si oriṣa wọn: Solomoni fà mọ awọn wọnyi ni ifẹ.

3 O si ni ẽdẹgbẹrin obinrin, awọn ọmọ ọba, ati ọ̃dunrun alè, awọn aya rẹ̀ si yi i li ọkàn pada.

4 O si ṣe, nigbati Solomoni di arugbo, awọn obinrin rẹ̀ yi i li ọkàn pada si ọlọrun miran: ọkàn rẹ̀ kò si ṣe dede pẹlu Oluwa Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi ọkàn Dafidi, baba rẹ̀.

5 Nitori Solomoni tọ Aṣtoreti lẹhin, oriṣa awọn ara Sidoni, ati Milkomu, irira awọn ọmọ Ammoni.

6 Solomoni si ṣe buburu niwaju Oluwa, kò si tọ̀ Oluwa lẹhin ni pipé gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀.

7 Nigbana ni Solomoni kọ́ ibi giga kan fun Kemoṣi, irira Moabu, lori oke ti mbẹ niwaju Jerusalemu, ati fun Moleki, irira awọn ọmọ Ammoni.

8 Bẹ̃li o si ṣe fun gbogbo awọn ajeji obinrin rẹ̀, awọn ti nsun turari, ti nwọn si nrubọ fun oriṣa wọn.

9 Oluwa si binu si Solomoni, nitori ọkàn rẹ̀ yipada kuro lọdọ Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti fi ara hàn a lẹrinmeji.

10 Ti o si paṣẹ fun u nitori nkan yi pe, Ki o má ṣe tọ̀ awọn ọlọrun miran lẹhin: ṣugbọn kò pa eyiti Oluwa fi aṣẹ fun u mọ́.

11 Nitorina Oluwa wi fun Solomoni pe, Nitori bi iwọ ti ṣe nkan yi, ti iwọ kò si pa majẹmu mi, ati aṣẹ mi mọ́, ti mo ti pa laṣẹ fun ọ, ni yiya emi o fà ijọba rẹ ya kuro lọwọ rẹ, emi o si fi i fun iranṣẹ rẹ.

12 Ṣugbọn emi ki yio ṣe e li ọjọ rẹ, nitori Dafidi baba rẹ; emi o fà a ya kuro lọwọ ọmọ rẹ.

13 Kiki pe emi kì yio fà gbogbo ijọba na ya; emi o fi ẹyà kan fun ọmọ rẹ, nitori Dafidi iranṣẹ mi, ati nitori Jerusalemu ti mo ti yàn.

Àwọn Ọ̀tá Solomoni

14 Oluwa si gbe ọta kan dide si Solomoni, Hadadi, ara Edomu: iru-ọmọ ọba li on iṣe ni Edomu.

15 O si ṣe, nigbati Dafidi wà ni Edomu, ati ti Joabu olori-ogun goke lọ lati sìn awọn ti a pa, nigbati o pa gbogbo ọkunrin ni Edomu.

16 Nitori oṣù mẹfa ni Joabu fi joko nibẹ ati gbogbo Israeli, titi o fi ké gbogbo ọkunrin kuro ni Edomu:

17 Hadadi si sá, on ati awọn ara Edomu ninu awọn iranṣẹ baba rẹ̀ pẹlu rẹ̀, lati lọ si Egipti; ṣugbọn Hadadi wà li ọmọde.

18 Nwọn si dide kuro ni Midiani, nwọn si wá si Parani; nwọn si mu enia pẹlu wọn lati Parani wá: nwọn si wá si Egipti, sọdọ Farao ọba Egipti, o si fun u ni ile kan, o si yàn onjẹ fun u, o si fun u ni ilẹ.

19 Hadadi si ri oju-rere pupọ̀ niwaju Farao, o si fun u li arabinrin aya rẹ̀, li aya, arabinrin Tapenesi, ayaba.

20 Arabinrin Tapenesi si bi Genubati ọmọ rẹ̀ fun u, Tapenesi si já a li ẹnu ọmu ni ile Farao: Genubati si wà ni ile Farao lãrin awọn ọmọ Farao,

21 Nigbati Hadadi si gbọ́ ni Egipti pe, Dafidi sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, ati pe Joabu olori-ogun si kú, Hadadi si wi fun Farao pe, rán mi lọ, ki emi ki o le lọ si ilu mi.

22 Nigbana ni Farao wi fun u pe, ṣugbọn kini iwọ ṣe alaini lọdọ mi, si kiyesi i, iwọ nwá ọ̀na lati lọ si ilu rẹ? O si wipe: Kò si nkan: ṣugbọn sa jẹ ki emi ki o lọ.

23 Pẹlupẹlu Ọlọrun gbe ọta dide si i; ani Resoni, ọmọ Eliada, ti o ti sá kuro lọdọ Hadadeseri oluwa rẹ̀, ọba Soba:

24 On si ko enia jọ sọdọ ara rẹ̀, o si di olori-ogun ẹgbẹ́ kan, nigbati Dafidi fi pa wọn, nwọn si lọ si Damasku, nwọn ngbe ibẹ, nwọn si jọba ni Damasku.

25 On si ṣe ọta si Israeli ni gbogbo ọjọ Solomoni, lẹhin ibi ti Hadadi ṣe: Resoni si korira Israeli, o si jọba lori Siria.

Ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún Jeroboamu

26 Ati Jeroboamu, ọmọ Nebati, ara Efrati ti Sereda, iranṣẹ Solomoni, orukọ iya ẹniti ijẹ Serua, obinrin opó kan, on pẹlu gbe ọwọ soke si ọba.

27 Eyi si ni idi ohun ti o ṣe gbe ọwọ soke si ọba: Solomoni kọ́ Millo, o si di ẹya ilu Dafidi baba rẹ̀.

28 Ọkunrin na, Jeroboamu, ṣe alagbara akọni: nigbati Solomoni si ri ọdọmọkunrin na pe, oṣiṣẹ enia ni, o fi i ṣe olori gbogbo iṣẹ-iru ile Josefu.

29 O si ṣe li àkoko na, nigbati Jeroboamu jade kuro ni Jerusalemu, woli Ahijah ara Ṣilo ri i loju ọ̀na; o si wọ̀ agbáda titun; awọn meji pere li o si mbẹ ni oko:

30 Ahijah si gbà agbáda titun na ti o wà lara rẹ̀, o si fà a ya si ọ̀na mejila:

31 O si wi fun Jeroboamu pe, Iwọ mu ẹya mẹwa: nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi pe, Wò o, emi o fa ijọba na ya kuro li ọwọ Solomoni, emi o si fi ẹya mẹwa fun ọ.

32 Ṣugbọn on o ni ẹya kan nitori Dafidi iranṣẹ mi, ati nitori Jerusalemu, ilu ti mo ti yàn ninu gbogbo ẹya Israeli:

33 Nitori ti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si mbọ Astoreti, oriṣa awọn ara Sidoni, ati Kemoṣi, oriṣa awọn ara Moabu, ati Milkomu, oriṣa awọn ọmọ Ammoni, nwọn kò si rin li ọ̀na mi, lati ṣe eyiti o tọ́ li oju mi, ati lati pa aṣẹ mi ati idajọ mi mọ́, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀.

34 Ṣugbọn emi kì yio gba gbogbo ijọba na lọwọ rẹ̀, ṣugbọn emi o ṣe e li ọmọ-alade ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀, nitori Dafidi, iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn, nitori o ti pa ofin mi ati aṣẹ mi mọ́:

35 Ṣugbọn emi o gba ijọba na li ọwọ ọmọ rẹ̀, emi o si fi i fun ọ, ani ẹya mẹwa.

36 Emi o si fi ẹya kan fun ọmọ rẹ̀, ki Dafidi iranṣẹ mi ki o le ni imọlẹ niwaju mi nigbagbogbo, ni Jerusalemu, ilu ti mo ti yàn fun ara mi lati fi orukọ mi sibẹ.

37 Emi o si mu ọ, iwọ o si jọba gẹgẹ bi gbogbo eyiti ọkàn rẹ nfẹ, iwọ o si jẹ ọba lori Israeli.

38 Yio si ṣe, bi iwọ o ba tẹtisilẹ si gbogbo eyiti mo paṣẹ fun ọ, ti iwọ o mã rin li ọ̀na mi, ti iwọ o si mã ṣe eyiti o tọ́ loju mi, lati pa aṣẹ mi ati ofin mi mọ́, gẹgẹ bi Dafidi iranṣẹ mi ti ṣe; emi o si wà pẹlu rẹ, emi o si kọ́ ile otitọ fun ọ, gẹgẹ bi emi ti kọ́ fun Dafidi, emi o si fi Israeli fun ọ.

39 Emi o si pọ́n iru-ọmọ Dafidi loju nitori eyi, ṣugbọn kì iṣe titi lai.

40 Nitorina Solomoni wá ọ̀na lati pa Jeroboamu. Jeroboamu si dide, o si sá lọ si Egipti si ọdọ Ṣiṣaki ọba Egipti, o si wà ni Egipti titi ikú Solomoni.

Ikú Solomoni

41 Ati iyokù iṣe Solomoni ati gbogbo eyiti o ṣe, ati ọgbọ́n rẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe iṣe Solomoni bi?

42 Ọjọ ti Solomoni jọba ni Jerusalemu lori gbogbo Israeli jẹ ogoji ọdun.

43 Solomoni si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i ni ilu Dafidi baba rẹ̀: Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22