1 BENHADADI, oba Siria si gbá gbogbo ogun rẹ̀ jọ: ọba mejilelọgbọn si mbẹ pẹlu rẹ̀ ati ẹṣin ati kẹkẹ́: o si gokè lọ, o si dóti Samaria, o ba a jagun.
2 O si rán awọn onṣẹ sinu ilu, sọdọ Ahabu, ọba Ìsraeli, o si wi fun u pe, Bayi ni Benhadadi wi.
3 Fadaka rẹ ati wura rẹ ti emi ni; awọn aya rẹ pẹlu ati awọn ọmọ rẹ, ani awọn ti o dara jùlọ, temi ni nwọn.
4 Ọba Israeli si dahùn o si wipe, oluwa mi, ọba, gẹgẹ bi ọ̀rọ rẹ tirẹ li emi, ati ohun gbogbo ti mo ni.
5 Awọn onṣẹ si tun padà wá, nwọn si wipe, Bayi ni Benhadadi sọ wipe, Mo tilẹ ranṣẹ si ọ wipe, Ki iwọ ki o fi fadaka rẹ ati wura rẹ, ati awọn aya rẹ, ati awọn ọmọ rẹ le mi lọwọ;
6 Nigbati emi ba rán awọn iranṣẹ mi si ọ ni iwòyi ọla, nigbana ni nwọn o wá ile rẹ wò, ati ile awọn iranṣẹ rẹ; yio si ṣe, ohunkohun ti o ba dara loju rẹ, on ni nwọn o fi si ọwọ́ wọn, nwọn o si mu u lọ.
7 Nigbana ni ọba Israeli pè gbogbo awọn àgba ilu, o si wipe, Ẹ fiyèsi i, emi bẹ̀ nyin, ki ẹ si wò bi ọkunrin yi ti nfẹ́ ẹ̀fẹ: nitoriti o ranṣẹ si mi fun awọn aya mi, ati fun awọn ọmọ mi, ati fun fadaka mi, ati fun wura mi, emi kò si fi dù u.
8 Ati gbogbo awọn àgba ati gbogbo awọn enia wi fun u pe, Máṣe fi eti si tirẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe gbà fun u.
9 Nitorina li o sọ fun awọn onṣẹ Benhadadi pe, Wi fun oluwa mi ọba pe, ohun gbogbo ti iwọ ranṣẹ fun, sọdọ iranṣẹ rẹ latetekọṣe li emi o ṣe: ṣugbọn nkan yi li emi kò le ṣe. Awọn onṣẹ na pada lọ, nwọn si tun mu èsi fun u wá.
10 Benhadadi si ranṣẹ si i, o si wipe, Ki awọn oriṣa ki o ṣe bẹ̃ si mi, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu bi ẽkuru Samaria yio to fun ikunwọ fun gbogbo enia ti ntẹle mi.
11 Ọba Israeli si dahùn, o si wipe, Wi fun u pe, Má jẹ ki ẹniti nhamọra, ki o halẹ bi ẹniti mbọ́ ọ silẹ,
12 O si ṣe, nigbati Benhadadi gbọ́ ọ̀rọ yi, bi o ti nmuti, on ati awọn ọba ninu agọ, li o sọ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ tẹ́gun si ilu na.
13 Si kiyesi i, woli kan tọ̀ Ahabu, ọba Israeli wá, wipe, Bayi li Oluwa wi, Iwọ ri gbogbo ọ̀pọlọpọ yi? kiyesi i, emi o fi wọn le ọ lọwọ loni; iwọ o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa.
14 Ahabu wipe, Nipa tani? On si wipe, Bayi li Oluwa wi, Nipa awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko. Nigbana li o wipe, Tani yio wé ogun na? On si dahùn pe: Iwọ.
15 Nigbana li o kà awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko, nwọn si jẹ igba o le mejilelọgbọn: lẹhin wọn li o si kà gbogbo awọn enia, ani gbogbo awọn ọmọ Israeli jẹ ẹdẹgbarin.
16 Nwọn si jade lọ li ọjọ-kanri. Ṣugbọn Benhadadi mu amupara ninu agọ, on, ati awọn ọba, awọn ọba mejilelọgbọn ti nràn a lọwọ.
17 Awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko tètekọ jade lọ: Benhadadi si ranṣẹ jade, nwọn si sọ fun u wipe, awọn ọkunrin nti Samaria jade wá.
18 On si wipe, Bi nwọn ba bá ti alafia jade, ẹ mu wọn lãye; tabi bi ti ogun ni nwọn ba bá jade, ẹ mu wọn lãye.
19 Bẹ̃ni awọn ipẹrẹ̀ wọnyi ti awọn ijoye igberiko jade ti ilu wá, ati ogun ti o tẹle wọn.
20 Nwọn si pa, olukuluku ọkunrin kọkan; awọn ara Siria sa; Israeli si lepa wọn: Benhadadi, ọba Siria si sala lori ẹṣin pẹlu awọn ẹlẹṣin.
21 Ọba Israeli si jade lọ, o si kọlu awọn ẹṣin ati kẹkẹ́, o pa awọn ara Siria li ọ̀pọlọpọ.
22 Woli na si wá sọdọ ọba Israeli, o si wi fun u pe, Lọ, mu ara rẹ giri, ki o si mọ̀, ki o si wò ohun ti iwọ nṣe: nitori li amọdun, ọba Siria yio goke tọ̀ ọ wá.
23 Awọn iranṣẹ ọba Siria si wi fun u pe, ọlọrun wọn, ọlọrun oke ni; nitorina ni nwọn ṣe li agbara jù wa lọ; ṣugbọn jẹ ki a ba wọn jà ni pẹtẹlẹ, awa o si li agbara jù wọn lọ nitõtọ.
24 Nkan yi ni ki o si ṣe, mu awọn ọba kuro, olukuluku kuro ni ipò rẹ̀, ki o si fi olori-ogun si ipò wọn.
25 Ki o si kà iye ogun fun ara rẹ gẹgẹ bi ogun ti o ti fọ́, ẹṣin fun ẹṣin, ati kẹkẹ́ fun kẹkẹ́: awa o si ba wọn jà ni pẹ̀tẹlẹ, nitõtọ awa o li agbara jù wọn lọ. O si fi eti si ohùn wọn, o si ṣe bẹ̃.
26 O si ṣe li amọdun, ni Benhadadi kà iye awọn ara Siria, nwọn si goke lọ si Afeki, lati bá Israeli jagun.
27 A si ka iye awọn ọmọ Israeli, nwọn si pese onjẹ, nwọn si lọ ipade wọn: awọn ọmọ Israeli si dó niwaju wọn gẹgẹ bi agbo ọmọ ewurẹ kekere meji: ṣugbọn awọn ara Siria kún ilẹ na.
28 Enia Ọlọrun kan si wá, o si sọ fun ọba Israeli, o si wipe, Bayi li Oluwa wi, Nitoriti awọn ara Siria wipe, Oluwa, Ọlọrun oke ni, ṣugbọn on kì iṣe Ọlọrun afonifoji, nitorina emi o fi gbogbo ọ̀pọlọpọ enia yi le ọ lọwọ́, ẹnyin o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa.
29 Nwọn si dó, ekini tì ekeji ni ijọ meje. O si ṣe, li ọjọ keje, nwọn padegun, awọn ọmọ Israeli si pa ọkẹ marun ẹlẹsẹ̀ ninu awọn ara Siria li ọjọ kan.
30 Sugbọn awọn iyokù salọ si Afeki, sinu ilu; odi si wolu ẹgbamẹtala-le-ẹgbẹrun ninu awọn enia ti o kù. Benhadadi si sa lọ, o si wá sinu ilu lati iyẹwu de iyẹwu.
31 Awọn iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Kiyesi i, nisisiyi, awa ti gbọ́ pe, awọn ọba ile Israeli, alãnu ọba ni nwọn: mo bẹ ọ, jẹ ki awa ki o fi aṣọ-ọ̀fọ si ẹgbẹ wa, ati ijará yi ori wa ka, ki a si jade tọ̀ ọba Israeli lọ: bọya on o gba ẹmi rẹ là.
32 Bẹ̃ni nwọn di aṣọ ọ̀fọ mọ ẹgbẹ wọn, nwọn si fi ijara yi ori wọn ka, nwọn si tọ̀ ọba Israeli wá, nwọn si wipe, Benhadadi, iranṣẹ rẹ, wipe, Emi bẹ ọ, jẹ ki ẹmi mi ki o yè. On si wipe, O mbẹ lãye sibẹ? arakunrin mi li on iṣe.
33 Awọn ọkunrin na si ṣe akiyesi gidigidi, nwọn si yara gbá ohun ti o ti ọdọ rẹ̀ wá mu: nwọn si wipe, Benhadadi arakunrin rẹ! Nigbana li o wipe, Ẹ lọ mu u wá. Nigbana ni Benhadadi jade tọ̀ ọ wá; o si mu u goke wá sinu kẹkẹ́.
34 On si wi fun u pe, Awọn ilu ti baba mi gbà lọwọ baba rẹ, emi o mu wọn pada: iwọ o si là ọ̀na fun ara rẹ ni Damasku, bi baba mi ti ṣe ni Samaria. Nigbana ni Ahabu wipe, Emi o rán ọ lọ pẹlu majẹmu yi. Bẹ̃ li o ba a dá majẹmu, o si rán a lọ.
35 Ọkunrin kan ninu awọn ọmọ awọn woli si wi fun ẹnikeji rẹ̀ nipa ọ̀rọ Oluwa pe, Jọ̃, lù mi. Ọkunrin na si kọ̀ lati lù u.
36 Nigbana li o wi pe, Nitoriti iwọ kò gbà ohùn Oluwa gbọ́, kiyesi i, bi iwọ ba ti ọdọ mi kuro, kiniun yio pa ọ. Bi o si ti jade lọ lọdọ rẹ̀, kiniun kan ri i o si pa a.
37 Nigbana li o si ri ọkunrin miran, o si wipe, Jọ̃, lù mi. Ọkunrin na si lù u, ni lilu ti o lù u, o pa a lara.
38 Woli na si lọ, o si duro de ọba loju ọ̀na, o pa ara rẹ̀ da, ni fifi ẽru ba oju.
39 Bi ọba si ti nkọja lọ, o ke si ọba o si wipe, iranṣẹ rẹ jade wọ arin ogun lọ; si kiyesi i, ọkunrin kan yà sapakan, o si mu ọkunrin kan fun mi wá o si wipe: Pa ọkunrin yi mọ; bi a ba fẹ ẹ kù, nigbana ni ẹmi rẹ yio lọ fun ẹmi rẹ̀, bi bẹ̃ kọ, iwọ o san talenti fadaka kan.
40 Bi iranṣẹ rẹ si ti ni iṣe nihin ati lọhun, a fẹ ẹ kù. Ọba Israeli si wi fun u pe, Bẹ̃ni idajọ rẹ yio ri: iwọ tikararẹ ti dá a.
41 O si yara, o si mu ẹ̃ru kuro li oju rẹ̀; ọba Israeli si ri i daju pe, ọkan ninu awọn woli ni on iṣe.
42 O si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, nitoriti iwọ jọwọ rẹ̀ lọwọ lọ, ọkunrin ti emi ti yàn si iparun patapata, ẹmi rẹ yio lọ fun ẹmi rẹ̀, ati enia rẹ fun enia rẹ̀.
43 Ọba Israeli si lọ si ile rẹ̀, o wugbọ, inu rẹ̀ si bajẹ o si wá si Samaria.