1 AHABU si sọ ohun gbogbo, ti Elijah ti ṣe, fun Jesebeli, ati pẹlu bi o ti fi idà pa gbogbo awọn woli.
2 Nigbana ni Jesebeli rán onṣẹ kan si Elijah, wipe, Bẹ̃ni ki awọn òriṣa ki o ṣe si mi ati jù bẹ̃ lọ pẹlu, bi emi kò ba ṣe ẹmi rẹ dabi ọkan ninu wọn ni iwoyi ọla.
3 O si bẹ̀ru, o si dide, o si lọ fun ẹmi rẹ̀, o si de Beerṣeba ti Juda, o si fi ọmọ-ọdọ rẹ̀ silẹ nibẹ.
4 Ṣugbọn on tikararẹ̀ lọ ni irin ọjọ kan si aginju, o si wá, o si joko labẹ igi juniperi kan, o si tọrọ fun ara rẹ̀ ki on ba le kú; o si wipe, O to; nisisiyi, Oluwa, gba ẹmi mi kuro nitori emi kò sàn jù awọn baba mi lọ!
5 Bi o si ti dùbulẹ ti o si sùn labẹ igi juniperi kan, si wò o, angeli fi ọwọ́ tọ́ ọ, o si wi fun u pe, Dide, jẹun.
6 O si wò, si kiyesi i, àkara ti a din lori ẹyin iná, ati orù-omi lẹba ori rẹ̀: o si jẹ, o si mu, o si tun dùbulẹ.
7 Angeli Oluwa si tun pada wá lẹrinkeji, o si fi ọwọ́ tọ́ ọ, o si wipe, Dide, jẹun; nitoriti ọ̀na na jìn fun ọ.
8 O si dide, o si jẹ, o mu, o si lọ li agbara onjẹ yi li ogoji ọsan ati ogoji oru si Horebu, oke Ọlọrun.
9 O si de ibẹ̀, si ibi ihò okuta, o si wọ̀ sibẹ, si kiyesi i, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Kini iwọ nṣe nihinyi, Elijah?
10 On si wipe, Ni jijowu emi ti njowu fun Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti kọ̀ majẹmu rẹ silẹ, nwọn ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ, nwọn si ti fi idà pa awọn woli rẹ: ati emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù, nwọn si nwá ẹmi mi lati gba a kuro.
11 O si wipe, Jade lọ, ki o si duro lori oke niwaju Oluwa. Si kiyesi i, Oluwa kọja, ìji nla ati lile si fà awọn oke nla ya, o si fọ́ awọn apata tũtu niwaju Oluwa; ṣugbọn Oluwa kò si ninu iji na: ati lẹhin iji na, isẹlẹ; ṣugbọn Oluwa kò si ninu isẹlẹ na.
12 Ati lẹhin isẹlẹ na, iná; ṣugbọn Oluwa kò si ninu iná na, ati lẹhin iná na, ohùn kẹ́lẹ kekere.
13 O si ṣe, nigbati Elijah gbọ́, o si fi agbáda rẹ̀ bo oju rẹ̀, o si jade lọ, o duro li ẹnu iho okuta na. Si kiyesi i, ohùn kan tọ̀ ọ wá wipe, Kini iwọ nṣe nihinyi Elijah?
14 On si wipe, Ni jijowu, emi ti njowu fun Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun: nitoriti awọn ọmọ Israeli ti kọ̀ majẹmu rẹ silẹ, nwọn si ti wó awọn pẹpẹ rẹ lulẹ, nwọn si ti fi idà pa awọn woli rẹ; ati emi, ani emi nikanṣoṣo li o kù; nwọn si nwá ẹmi mi lati gba a kuro.
15 Oluwa si wi fun u pe, Lọ, pada li ọ̀na rẹ, kọja li aginju si Damasku: nigbati iwọ ba de ibẹ, ki o si fi ororo yan Hasaeli li ọba lori Siria.
16 Ati Jehu, ọmọ Nimṣi ni iwọ o fi ororo yàn li ọba lori Israeli: ati Eliṣa, ọmọ Ṣafati, ara Abel-Mehola ni iwọ o fi ororo yan ni woli ni ipò rẹ.
17 Yio si ṣe, ẹniti o ba sala kuro lọwọ idà Hasaeli ni Jehu yio pa, ati ẹniti o ba sala kuro lọwọ idà Jehu ni Eliṣa yio pa.
18 Ṣugbọn emi ti kù ẹ̃dẹgbarin enia silẹ fun ara mi ni Israeli, gbogbo ẽkun ti kò tii kunlẹ fun Baali, ati gbogbo ẹnu ti kò iti fi ẹnu kò o li ẹnu.
19 Bẹ̃ni o pada kuro nibẹ, o si ri Eliṣa, ọmọ Ṣafati o nfi àjaga malu mejila tulẹ niwaju rẹ̀, ati on na pẹlu ikejila: Elijah si kọja tọ̀ ọ lọ, o si da agbáda rẹ̀ bò o.
20 O si fi awọn malu silẹ o si sare tọ̀ Elijah lẹhin o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki emi lọ ifi ẹnu kò baba ati iya mi li ẹnu, nigbana ni emi o tọ̀ ọ lẹhin. O si wi fun u pe, Lọ, pada, nitori kini mo fi ṣe ọ?
21 O si pada lẹhin rẹ̀, o si mu àjaga malu kan, o si pa wọn, o si fi ohun-elo awọn malu na bọ̀ ẹran wọn, o si fi fun awọn enia, nwọn si jẹ. On si dide, o si tẹle Elijah lẹhin, o si ṣe iranṣẹ fun u.