1 NIGBATI ayaba Ṣeba si gbọ́ okiki Solomoni niti orukọ Oluwa, o wá lati fi àlọ dán a wò.
2 O si wá si Jerusalemu pẹlu ẹgbẹ nlanla, ibakasiẹ ti o ru turari, ati ọ̀pọlọpọ wura, ati okuta oniyebiye: nigbati o si de ọdọ Solomoni o ba a sọ gbogbo eyiti mbẹ li ọkàn rẹ̀.
3 Solomoni si fi èsi si gbogbo ọ̀rọ rẹ̀, kò si ibère kan ti o pamọ fun ọba ti kò si sọ fun u.
4 Nigbati ayaba Ṣeba si ti ri gbogbo ọgbọ́n Solomoni, ati ile ti o ti kọ́.
5 Ati onjẹ tabili rẹ̀, ati ijoko awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀, ati iduro awọn iranṣẹ rẹ̀, ati iwọṣọ wọn, ati awọn agbọti rẹ̀, ati ọna ti o mba goke lọ si ile Oluwa; kò kù agbara kan fun u mọ.
6 O si wi fun ọba pe, Otitọ li ọ̀rọ ti mo gbọ́ ni ilẹ mi niti iṣe rẹ ati niti ọgbọ́n rẹ.
7 Ṣugbọn emi kò gba ọ̀rọ na gbọ́, titi mo fi de, ti oju mi si ti ri: si kiyesi i, a kò sọ idajì wọn fun mi: iwọ si ti fi ọgbọ́n ati irọra kún okiki ti mo gbọ́.
8 Ibukún ni fun awọn enia rẹ, ibukún ni fun awọn iranṣẹ rẹ wọnyi, ti nduro niwaju rẹ nigbagbogbo, ti ngbọ́ ọgbọ́n rẹ.
9 Alabukún fun li Oluwa Ọlọrun rẹ, ti o ni inu-didùn si ọ lati gbe ọ ka ori itẹ́ Israeli: nitoriti Oluwa fẹràn Israeli titi lai, nitorina li o ṣe fi ọ jọba, lati ṣe idajọ ati otitọ.
10 On si fun ọba li ọgọfa talenti wura, ati turari lọ́pọlọpọ ati okuta iyebiye: iru ọ̀pọlọpọ turari bẹ̃ kò de mọ bi eyiti ayaba Ṣeba fi fun Solomoni, ọba.
11 Pẹlupẹlu awọn ọ̀wọ-ọkọ̀ Hiramu ti o mu wura lati Ofiri wá, mu igi Algumu, (igi Sandali) lọpọlọpọ ati okuta oniyebiye lati Ofiri wá.
12 Ọba si fi igi Algumu na ṣe opó fun ile Oluwa, ati fun ile ọba dùru pẹlu ati ohun-elo orin miran fun awọn akọrin: iru igi Algumu bẹ̃ kò de mọ, bẹ̃ni a kò ri wọn titi di oni yi.
13 Solomoni ọba si fun ayaba Ṣeba ni gbogbo ifẹ rẹ̀, ohunkohun ti o bère, li aika eyiti a fi fun u lati ọwọ Solomoni ọba wá. Bẹ̃li o si yipada, o si lọ si ilu rẹ̀, on, ati awọn iranṣẹ rẹ̀.
14 Njẹ ìwọn wura ti o nde ọdọ Solomoni li ọdun kan, jẹ ọtalelẹgbẹta o le mẹfa talenti wura,
15 Laika eyi ti o ngbà lọwọ awọn ajẹlẹ ati awọn oniṣowo, ati ti gbogbo awọn ọba Arabia, ati ti awọn bãlẹ ilẹ.
16 Solomoni ọba si ṣe igba asà wura lilù: ẹgbẹta ṣekeli wura li o tán si asà kan.
17 O si ṣe ọdunrun apata wura lilù, oṣuwọn wura mẹta li o tán si apata kan: ọba si ko wọn si ile igbo Lebanoni.
18 Ọba si ṣe itẹ́ ehin-erin kan nla, o si fi wura didara julọ bò o.
19 Itẹ́ na ni atẹgùn mẹfa, oke itẹ́ na yi okiribiti lẹhin: irọpá si wà niha kini ati ekeji ni ibi ijoko na, kiniun meji si duro lẹba na.
20 Kiniun mejila duro nibẹ niha ekini ati ekeji lori atẹgùn mẹfa na: a kò ṣe iru rẹ̀ ni ijọba kan.
21 Ati gbogbo ohun-elo mimu Solomoni ọba jẹ wura, ati gbogbo ohun-elo ile igbo Lebanoni jẹ wura daradara; kò si fadaka; a kò kà a si nkankan li ọjọ Solomoni.
22 Nitori ọba ni ọkọ̀ Tarṣiṣi kan pẹlu ọkọ̀ Hiramu li okun: ẹ̃kan li ọdun mẹta li ọkọ̀ Tarṣiṣi idé, ti imu wura ati fadaka, ehin-erin ati inakí ati ẹiyẹ-ologe wá.
23 Solomoni ọba si pọ̀ jù gbogbo awọn ọba aiye lọ, li ọrọ̀ ati li ọgbọ́n.
24 Gbogbo aiye si nwá oju Solomoni, lati gbọ́ ọgbọ́n rẹ̀, ti Ọlọrun ti fi si i li ọkàn.
25 Olukuluku nwọn si mu ọrẹ tirẹ̀ wá, ohun-elo fadaka, ati ohun-elo wura, ati ẹ̀wu, ati turari, ẹṣin ati ibãka, iye kan lọdọdun.
26 Solomoni si ko kẹkẹ́ ati èṣin jọ: o si ni egbeje kẹkẹ́ ati ẹgbãfa ẹlẹsin, o si fi wọn si ilu kẹkẹ́, ati pẹlu ọba ni Jerusalemu.
27 Ọba si ṣe ki fadakà ki o wà ni Jerusalemu bi okuta, ati igi kedari li o ṣe ki o dabi igi sikamore ti mbẹ ni afonifoji fun ọ̀pọlọpọ.
28 A si mu ẹṣin wá fun Solomoni lati Egipti li ọwọ́wọ, oniṣowo ọba nmu wọn wá fun owo.
29 Kẹkẹ́ kan ngoke o si njade lati Egipti wá fun ẹgbẹta ṣekeli fadakà, ati ẹṣin kan fun ãdọjọ: bẹ̃ni nwọn si nmu wá pẹlu nipa ọwọ wọn fun gbogbo awọn ọba awọn ọmọ Hiti ati fun awọn ọba Siria.