1 O si ṣe, ni ọrinlenirinwo ọdun, lẹhin igbati awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti, li ọdun kẹrin ijọba Solomoni lori Israeli, li oṣu Sifi ti iṣe oṣu keji, li o bẹ̀rẹ si ikọ́ ile fun Oluwa.
2 Ile na ti Solomoni ọba kọ́ fun Oluwa, gigun rẹ̀ jẹ ọgọta igbọnwọ, ibú rẹ̀, ogun igbọnwọ, ati giga rẹ̀, ọgbọn igbọnwọ.
3 Ati ọ̀dẹdẹ niwaju tempili ile na, ogún igbọnwọ ni gigùn rẹ̀, gẹgẹ bi ibú ile na: igbọnwọ mẹwa si ni ibú rẹ̀ niwaju ile na.
4 Ati fun ile na ni a ṣe ferese fun síse.
5 Lara ogiri ile na li o bù yàra yika; ati tempili, ati ibi-mimọ́-julọ, li o si ṣe yara yika.
6 Yara isalẹ, igbọnwọ marun ni gbigbòro rẹ̀, ti ãrin, igbọnwọ mẹfa ni gbigbòro rẹ̀, ati ẹkẹta, igbọnwọ meje ni gbigbòro rẹ̀, nitori lode ogiri ile na li o dín igbọnwọ kọ̃kan kakiri, ki igi-àja ki o má ba wọ inu ogiri ile na.
7 Ile na, nigbati a nkọ́ ọ, okuta ti a ti gbẹ́ silẹ ki a to mu u wá ibẹ li a fi kọ́ ọ, bẹ̃ni a kò si gburo mataka, tabi ãke, tabi ohun-elo irin kan nigbati a nkọ́ ọ lọwọ.
8 Ilẹkun yara ãrin mbẹ li apa ọtún ile na: nwọn si fi àtẹgun ti o lọ́ri goke sinu yàra ãrin, ati lati yara ãrin bọ sinu ẹkẹta.
9 Bẹ̃li o kọ́ ile na, ti o si pari rẹ̀: o si fi gbelerù ati apako kedari bò ile na.
10 O si kọ́ yara gbè gbogbo ile na, igbọnwọ marun ni giga: o fi ìti kedari mú wọn fi ara ti ile na.
11 Ọ̀rọ Oluwa si tọ Solomoni wá wipe,
12 Nipa ti ile yi ti iwọ nkọ́ lọwọ nì, bi iwọ o ba rin ninu aṣẹ mi, ti iwọ o si ṣe idajọ mi, ati ti iwọ o si pa gbogbo ofin mi mọ lati ma rin ninu wọn, nigbana ni emi o mu ọ̀rọ mi ṣẹ pẹlu rẹ, ti mo ti sọ fun Dafidi, baba rẹ;
13 Emi o si ma gbe ãrin awọn ọmọ Israeli, emi kì o si kọ̀ Israeli, enia mi.
14 Solomoni si kọ́ ile na, o si pari rẹ̀.
15 O si fi apako kedari tẹ́ ogiri ile na ninu, lati ilẹ ile na de àja rẹ̀; o fi igi bò wọn ninu, o si fi apako firi tẹ́ ilẹ ile na.
16 O si kọ́ ogún igbọnwọ ni ikangun ile na, lati ilẹ de àja ile na li o fi apako kedari kọ́, o tilẹ kọ́ eyi fun u ninu, fun ibi-idahùn, ani ibi-mimọ́-julọ.
17 Ati ile na, eyini ni Tempili niwaju rẹ̀, jẹ ogoji igbọnwọ ni gigùn.
18 Ati kedari ile na ninu ile li a fi irudi ati itanna ṣe iṣẹ ọnà rẹ̀: gbogbo rẹ̀ kiki igi kedari; a kò ri okuta kan.
19 Ibi-mimọ́-julọ na li o mura silẹ ninu ile lati gbe apoti majẹmu Oluwa kà ibẹ.
20 Ibi-mimọ́-julọ na si jasi ogún igbọnwọ ni gigùn, li apa ti iwaju, ati ogún igbọnwọ ni ibú, ati ogún igbọnwọ ni giga rẹ̀; o si fi wura ailadàlu bò o, bẹ̃li o si fi igi kedari bò pẹpẹ.
21 Solomoni si fi wura ailadàlu bò ile na ninu: o si fi ẹwọ́n wura ṣe oju ibi-mimọ́-julọ, o si fi wura bò o.
22 Gbogbo ile na li o si fi wura bò titi o fi pari gbogbo ile na; ati gbogbo pẹpẹ ti o wà niha ibi-mimọ́-julọ li o fi wura bò.
23 Ati ninu ibi-mimọ́-julọ li o fi igi olifi ṣe kerubu meji, ọkọkan jẹ igbọnwọ mẹwa ni giga.
24 Ati igbọnwọ marun ni apa kerubu kan, ati igbọnwọ marun ni apa kerubu keji; lati igun apakan titi de igun apa-keji jẹ igbọnwọ mẹwa.
25 Igbọnwọ mẹwa si ni kerubu keji: kerubu mejeji jẹ ìwọn kanna ati titobi kanna.
26 Giga kerubu kan jẹ igbọnwọ mẹwa, bẹ̃ni ti kerubu keji.
27 O si fi awọn kerubu sinu ile ti inu lọhun, nwọn si nà iyẹ-apa kerubu na, tobẹ̃ ti iyẹ-apa ọkan si kàn ogiri kan, ati iyẹ-apa kerubu keji si kàn ogiri keji: iyẹ-apa wọn si kàn ara wọn larin ile na.
28 O si fi wura bò awọn kerubu na.
29 O si yá aworan awọn kerubu lara gbogbo ogiri ile na yikakiri ati ti igi-ọpẹ, ati ti itanna eweko, ninu ati lode.
30 Ilẹ ile na li o fi wura tẹ́ ninu ati lode.
31 Ati fun oju-ọ̀na ibi-mimọ́-julọ li o ṣe ilẹkùn igi olifi: itẹrigbà ati opó ihà jẹ idamarun ogiri.
32 Ilẹkùn mejeji na li o si fi igi olifi ṣe; o si yá aworan awọn kerubu ati ti igi-ọpẹ, ati ti itanna eweko sara wọn, o si fi wura bò wọn, o si nà wura si ara awọn kerubu, ati si ara igi-ọpẹ.
33 Bẹ̃li o si ṣe opó igi olifi olorigun mẹrin fun ilẹkun tempili na.
34 Ilẹkun mejeji si jẹ ti igi firi: awẹ́ meji ilẹkun kan jẹ iṣẹ́po, ati awẹ́ meji ilẹkun keji si jẹ iṣẹ́po.
35 O si yá awọn kerubu, ati igi-ọpẹ, ati itanna eweko si ara wọn: o si fi wura bò o, eyi ti o tẹ́ sori ibi ti o gbẹ́.
36 O si fi ẹsẹsẹ mẹta okuta gbigbẹ́, ati ẹsẹ kan ìti kedari kọ́ agbala ti inu ọhun.
37 Li ọdun kẹrin li a fi ipilẹ ile Oluwa le ilẹ̀, li oṣu Sifi.
38 Ati li ọdun kọkanla, li oṣu Bulu, ti iṣe oṣu kẹjọ, ni ile na pari jalẹ-jalẹ, pẹlu gbogbo ipin rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti o yẹ: o si fi ọdun meje kọ́ ọ.