1. A. Ọba 13 YCE

1 SI kiyesi i, enia Ọlọrun kan lati Juda wá si Beteli nipa ọ̀rọ Oluwa: Jeroboamu duro lẹba pẹpẹ lati fi turari jona.

2 O si kigbe si pẹpẹ na nipa ọ̀rọ Oluwa, o si wipe, Pẹpẹ! pẹpẹ! bayi li Oluwa wi, Kiyesi i, a o bi ọmọ kan ni ile Dafidi, Josiah li orukọ rẹ̀; lori rẹ ni yio si fi awọn alufa ibi giga wọnni ti nfi turari jona lori rẹ rubọ, a o si sun egungun enia lori rẹ.

3 O si fun wọn li àmi kan li ọjọ kanna wipe, Eyi li àmi ti Oluwa ti ṣe; Kiyesi i, pẹpẹ na yio ya, ẽru ti mbẹ lori rẹ̀ yio si danu.

4 O si ṣe, nigbati Jeroboamu, ọba gbọ́ ọ̀rọ enia Ọlọrun, ti o ti kigbe si pẹpẹ na, o wipe, Ẹ mu u. Ọwọ́ rẹ̀ ti o nà si i, si gbẹ, bẹ̃ni kò si le fa a pada sọdọ rẹ̀ mọ.

5 Pẹpẹ na si ya, ẽru na si danù kuro ninu pẹpẹ na, gẹgẹ bi àmi ti enia Ọlọrun ti fi fun u nipa ọ̀rọ Oluwa.

6 Ọba si dahùn, o si wi fun enia Ọlọrun na pe, Tù Oluwa Ọlọrun rẹ loju nisisiyi, ki o si gbadura fun mi, ki a ba le tun mu ọwọ́ mi bọ̀ sipo fun mi. Enia Ọlọrun na si tù Ọlọrun loju, a si tun mu ọwọ́ ọba bọ̀ sipo fun u, o si dàbi o ti wà ri.

7 Ọba si wi fun enia Ọlọrun na pe, Wá ba mi lọ ile, ki o si tù ara rẹ lara, emi o si ta ọ li ọrẹ.

8 Enia Ọlọrun na si wi fun ọba pe, Bi iwọ o ba fun mi ni idaji ile rẹ, emi kì yio ba ọ lọ ile, emi kì yio si jẹ onjẹ, bẹ̃ni emi kì yio si mu omi nihin yi.

9 Nitori bẹ̃ li a pa a laṣẹ fun mi nipa ọ̀rọ Oluwa wipe, Máṣe jẹ onjẹ, má si ṣe mu omi, bẹ̃ni ki o má si ṣe pada li ọ̀na kanna ti o ba wá.

10 Bẹ̃ li o si ba ọ̀na miran lọ, kò si pada li ọ̀na na ti o gbà wá si Beteli.

Wolii Àgbàlagbà Kan, Ará Bẹtẹli

11 Woli àgba kan si ngbe Beteli: ọmọ rẹ̀ de, o si rohin gbogbo iṣẹ ti enia Ọlọrun na ti ṣe li ọjọ na ni Beteli fun u: ọ̀rọ ti o sọ fun ọba nwọn si sọ fun baba wọn.

12 Baba wọn si wi fun wọn pe, Ọna wo li o gbà? Nitori awọn ọmọ rẹ̀ ti ri ọ̀na ti enia Ọlọrun na gbà, ti o ti Juda wá.

13 O si wi fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun mi. Nwọn si di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun u o si gùn u.

14 O si tẹ̀le enia Ọlọrun na lẹhin, o si ri i, o joko labẹ igi nla kan: o si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun na ti o ti Juda wá? On si wipe, Emi ni.

15 O si wi fun u pe, Ba mi lọ ile, ki o si jẹ onjẹ.

16 On si wipe, Emi kò lè pada lọ pẹlu rẹ, bẹ̃ni emi kò lè ba ọ lọ: bẹ̃ni emi kì o jẹ onjẹ, emi kì o si mu omi pẹlu rẹ nihin yi.

17 Nitori ti a sọ fun mi nipa ọ̀rọ Oluwa pe, Iwọ kò gbọdọ jẹ onjẹ, iwọ kò si gbọdọ mu omi nibẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ tun pada lọ nipa ọ̀na ti iwọ ba wá.

18 O si wi fun u pe, Woli li emi pẹlu gẹgẹ bi iwọ; angeli si sọ fun mi nipa ọ̀rọ Oluwa wipe, Mu u ba ọ pada sinu ile rẹ, ki o le jẹ onjẹ ki o si le mu omi. Ṣugbọn o purọ fun u.

19 Bẹ̃ li o si ba a pada lọ, o si jẹ onjẹ ni ile rẹ̀, o si mu omi.

20 O si ṣe, bi nwọn ti joko ti tabili, li ọ̀rọ Oluwa tọ woli na wá ti o mu u padà bọ̀:

21 O si kigbe si enia Ọlọrun ti o ti Juda wá wipe, bayi li Oluwa wi: Niwọn bi iwọ ti ṣe aigbọran si ẹnu Oluwa, ti iwọ kò si pa aṣẹ na mọ ti Oluwa Ọlọrun rẹ pa fun ọ.

22 Ṣugbọn iwọ pada, iwọ si ti jẹ onjẹ, iwọ si ti mu omi ni ibi ti Oluwa sọ fun ọ pe, Máṣe jẹ onjẹ, ki o má si ṣe mu omi; okú rẹ kì yio wá sinu iboji awọn baba rẹ.

23 O si ṣe, lẹhin igbati o ti jẹ onjẹ, ati lẹhin igbati o ti mu, li o di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun u, eyini ni, fun woli ti o ti mu pada bọ̀.

24 Nigbati o si lọ tan, kiniun kan pade rẹ̀ li ọ̀na, o si pa a: a si gbe okú rẹ̀ sọ si oju ọ̀na, kẹtẹkẹtẹ si duro tì i, kiniun pẹlu duro tì okú na.

25 Si kiyesi i, awọn enia nkọja, nwọn ri pe, a gbe okú na sọ si oju ọ̀na, kiniun na si duro tì okú na: nwọn si wá, nwọn si sọ ọ ni ilu ti woli àgba na ngbe.

26 Nigbati woli ti o mu u lati ọ̀na pada bọ̀ gbọ́, o wipe, Enia Ọlọrun na ni, ti o ṣọ̀tẹ si Oluwa: nitorina li Oluwa fi i le kiniun lọwọ, ti o si fà a ya, ti o si pa a, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o ti sọ fun u.

27 O si wi fun awọn ọmọ rẹ̀ pe, Ẹ di kẹtẹkẹtẹ ni gari fun mi. Nwọn si di i ni gari.

28 O si lọ, o si ri, a gbé okú rẹ̀ sọ si oju ọ̀na, ati kẹtẹkẹtẹ, ati kiniun duro ti okú na, kiniun kò jẹ okú na, bẹ̃ni kò fà kẹtẹkẹtẹ na ya.

29 Woli na mu okú enia Ọlọrun na, o si gbé e lori kẹtẹkẹtẹ na, o si mu u pada bọ̀: woli àgba na si wá si ilu, lati ṣọ̀fọ, ati lati sin i.

30 O si tẹ okú rẹ̀ sinu iboji ara rẹ̀: nwọn si sọ̀fọ lori rẹ̀, pe: O ṣe, arakunrin mi!

31 O si ṣe, lẹhin igbati o ti sinkú rẹ̀ tan, o si sọ fun awọn ọmọ rẹ̀ wipe, Nigbati mo ba kú, nigbana ni ki ẹ sinkú mi ni iboji ninu eyiti a sin enia Ọlọrun; ẹ tẹ́ egungun mi lẹba egungun rẹ̀:

32 Nitori ni ṣiṣẹ, ọ̀rọ ti o kigbe nipa ọ̀rọ Oluwa si pẹpẹ na ni Beteli, ati si gbogbo ile ibi giga ti mbẹ ni gbogbo ilu Samaria, yio ṣẹ dandan.

Ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣe ikú pa Jeroboamu

33 Lẹhin nkan yi, Jeroboamu kò pada kuro ninu ọ̀na ibi rẹ̀, ṣugbọn o tun mu ninu awọn enia ṣe alufa ibi giga wọnni: ẹnikẹni ti o ba fẹ, a yà a sọtọ̀ on a si di alufa ibi giga wọnni.

34 Nkan yi si di ẹ̀ṣẹ ile Jeroboamu, ani lati ke e kuro, ati lati pa a run kuro lori ilẹ.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22