22 Nitori ọba ni ọkọ̀ Tarṣiṣi kan pẹlu ọkọ̀ Hiramu li okun: ẹ̃kan li ọdun mẹta li ọkọ̀ Tarṣiṣi idé, ti imu wura ati fadaka, ehin-erin ati inakí ati ẹiyẹ-ologe wá.
23 Solomoni ọba si pọ̀ jù gbogbo awọn ọba aiye lọ, li ọrọ̀ ati li ọgbọ́n.
24 Gbogbo aiye si nwá oju Solomoni, lati gbọ́ ọgbọ́n rẹ̀, ti Ọlọrun ti fi si i li ọkàn.
25 Olukuluku nwọn si mu ọrẹ tirẹ̀ wá, ohun-elo fadaka, ati ohun-elo wura, ati ẹ̀wu, ati turari, ẹṣin ati ibãka, iye kan lọdọdun.
26 Solomoni si ko kẹkẹ́ ati èṣin jọ: o si ni egbeje kẹkẹ́ ati ẹgbãfa ẹlẹsin, o si fi wọn si ilu kẹkẹ́, ati pẹlu ọba ni Jerusalemu.
27 Ọba si ṣe ki fadakà ki o wà ni Jerusalemu bi okuta, ati igi kedari li o ṣe ki o dabi igi sikamore ti mbẹ ni afonifoji fun ọ̀pọlọpọ.
28 A si mu ẹṣin wá fun Solomoni lati Egipti li ọwọ́wọ, oniṣowo ọba nmu wọn wá fun owo.